Poopu ijọ Aguda, to tun jẹ Bisọọpu ilẹ Roomu, Pope Francis, ti jade laye.
Ẹni ọdun mejidinlaadọrun ni ojiṣẹ Ọlọrun naa ki iku to pa oju rẹ de laarọ ọjọ Mọnde, ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹrin ọdun yii.
Iṣẹlẹ yii waye lẹyin wakati diẹ ti awọn olujọsin korajọ si Vatican ni Saint Peter's Basillica nibi ti Poopu ti ba wọn sọrọ ajinde, to si gbadura fun wọn.
No comments:
Post a Comment