Ọmọbibi agboole Balogun-bii-irọ niluu Oṣogbo ni Saheed Babatunde ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ti ọwọ ajọ Amọtẹkun ipinlẹ Ọṣun tẹ laipẹ yii lori ẹsun ole jija.
Aago mẹjọ alẹ ọjọ Wẹsidee ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹrin ọdun yii ni Saheed lọ ji pọọti idana lagbegbe Isalẹ Ọṣun.
Gẹgẹ bi alakoso ajọ Amọtẹkun l'Ọṣun, Dokita Adekunle Ọmọyẹle, ṣe ṣalaye, ẹnikan to kofirii Saheed lo ta awọn amọtẹkun lolobo, ọwọ si tẹ ẹ nibi to sapamọ si.
Saheed sọ fun Gbagedeọrọ pe nitori pe ko si owo ti oun yoo fi ṣekọmọ ọmọ oun lo fa a ti oun fi lọọ jale.
O ni ẹgbẹrun mẹrin naira pere ni oun ta gbogbo isaasun ti oun ji fun ọkunrin Hausa kan.
Amọ ṣa, Ọmọyẹle ṣalaye owo awọn isaasun ti Saheed ji to ẹgbẹrun lọna okoodinlọọdunrun naira.
O ni yoo foju bale ẹjọ lẹyin iwadii nitori akọsilẹ ti fi han pe o ti kọkọ lọ sẹwọn ri.
Hello editor,the guy named Saheed who said it was because of name ceremony that makes him to commit stealing and burgling was a lier,he was an ex-convict he was convicted for murder and vandalization and was sentence to a year plus2020.he was released June 2021, since his release he has becoming terror to the community.he has been arrested at dugbe police station for stealing also by Amotekun corps osogbo command three times,he has been detained once broken the cell, before he was re-arrested by Amotekun corps osogbo command after he broke one woman popularly called iya ijesha shop and cast away cooking pots and refrigerator also operated at national museum groove osogbo .
ReplyDelete