IROYIN YAJOYAJO

Friday, 25 April 2025

Ọna ti n la, o si ti han pe a maa gba ipinlẹ Ọṣun lọdun 2026 - Igbimọ Agba Ọṣun


Igbimọ Agba Ọṣun ninu ẹgbẹ All Progressives Congress, labẹ alaga wọn, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, ti sọ pe gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ bayii ti fi han pe pẹlu irọrun lẹgbẹ naa yoo gba akoso ipinlẹ Ọṣun pada lọdun 2026.


Nibi ipade oloṣooṣu wọn to waye niluu Ileefẹ nilee alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun, Sooko Tajudeen Lawal ni wọn ti ke si awọn oloye ẹgbẹ lati ri i daju pe wọn n ba  gbogbo awọn oludije funpo gomina jiroro loorekoore fun itọni.


Wọn tun ke si awọn ọmọ ẹgbẹ lati maṣe ṣe ohunkohun lẹyin awọn oloye nitori iṣọkan ṣe pataki laarin wọn, paapaa lasiko yii ti idibo gomina ti sunmọle.


Lọjọ naa ni Igbimọ Agba Ọṣun gba Alhaji Issah A. Niniọla si aarin wọn, ti wọn si sọ pe aṣeyọri ẹgbẹ naa daju pẹluu bii awọn opomulero ẹgbẹ PDP bii Hon. Wọle Ọkẹ ṣe n darapọ mọ APC bayii.

No comments:

Post a Comment