IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 9 April 2025

Njẹ ẹ ti gbọ? Awọn ara Osun West fontẹ lu Gomina Adeleke fun saa keji, wọn ni ko sẹni to tun le ṣe bii tiẹ


Bi idibo gomina ṣe n kanlẹkun nipinlẹ Ọṣun, awọn eeyan agbegbe Iwọ-Oorun Ọṣun ti sọ pe Gomina Ademọla Adeleke yoo lọ fun saa keji rẹ lọdun 2026.


Nibi ipade awọn oloye ẹgbẹ oṣelu PDP atawọn agbalagba ni ẹkun idibo naa, nibi ti Sẹnetọ wọn, Akọgun Lere Oyewumi ti gba wọn lalejo, ni wọn ti sọ pe gomina ti ṣe takuntakun laarin ọdun meji ataabọ to ti de ori aleefa.


Alaga ẹgbẹ PDP nijọba ibilẹ Iwo, Hon. Alidu Adeoye lo dabaa pe ki wọn fontẹ lu Gomina Adeleke fun saa keji ṣaaju idibo 2026 lorukọ awọn oloye ẹgbẹ to ṣẹku.


O ni ko sẹni to gbọdọ ba Adeleke du tikẹẹti naa latari awọn oniruuru iṣẹ idagbasoke to ti wọnu ipinlẹ Ọṣun lasiko rẹ.


Oludamọran lori ọrọ ofin fun ẹgbẹ naa, Amofin Ebenezer Bọlarinwa lo kéjì aba naa niwaju awọn to wa nibi ipade ọhun bii Hon. Ọdẹlade, Mrs Atinukẹ Ọyawọye, Alhaji Fatai Akinbade, Hon. Mudashiru Lukman ati bẹẹ bẹẹ lọ.


Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Gomina Adeleke, ẹni ti olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina, Alhaji Kazeem Akinlẹyẹ ṣoju fun, dupẹ lọwọ awọn oloye ati agbaagba ẹgbẹ ni Iwọ Oorun Ọṣun fun igbagbọ ti wọn ni ninu rẹ.


O ṣeleri pe gbogbo ohun to wa ninu ileri ẹlẹka marun-un ti gomina ṣe fawọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ni yoo ṣe patapata ki saa akọkọ yii to pari.


Ninu ọrọ tirẹ, Akọgun Oyewumi sọ pe Adeleke ti ṣe daradara pupọ to fi lẹtọọ si saa keji. O ni idije laarin ohun rere ati ohun buburu ni idibo ọdun 2026, Gomina Adeleke si jẹ ami ohun rere l'Ọṣun titi di ọdun 2030.


O ni 'A n fi asiko yii kede fawọn eeyan ipinlẹ Ọṣun pe a tun fẹẹ gbe ọmọ wa, adari wa, Ademọla Adeleke kalẹ fun saa keji loṣu keje ọdun 2026'


Bakan naa ni akọwe ijọba nigba kan ri l'Ọṣun, Alhaji Fatai Akinbade to ṣoju awọn agbaagba ẹgbẹ ṣalaye pe Gomina Adeleke ti dari ipinlẹ Ọṣun pẹlu ọgbọn inu ati akoyawọ, nitori naa, o tọ si saa keji fun itẹsiwaju iṣẹ rere.

No comments:

Post a Comment