John Uba, ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn ni ọwọ awọn ajọ Amọtẹkun ipinlẹ Ọṣun ti tẹ bayii lori ẹsun ole jija.
Gbagedeọrọ gbọ pe akolo awọn ọlọpaa to wa ni Ọta-̣Ẹfun niluu Oṣogbo ni John wa tẹlẹ nibi ti wọn ti i mọ, ṣugbọn ko sẹni to mọ bo ṣe sa mọ wọn lọwọ nibẹ.
Bo ṣe kuro nibẹ lo pada sidi iṣẹ ole, oru ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹrin ọdun yii ni ọwọ awọn Amọtẹkun si tẹ ẹ lasiko to n jale lọwọ lagbegbe Fiwaṣaye niluu Oṣogbo.
John jẹwọ lọdọ awọn Amọtẹkun pe aimọye igba ni wọn ti mu oun lori ẹsun ole jija, foonu atawọn nnkan miran loun atawọn alabaṣiṣẹpọ oun si maa n ji.
Alakoso ajọ Amọtẹkun l'Ọṣun, Adekunle Ọmọyẹle, sọ pe awọn ti pada fa ọmọkunrin naa le awọn ọlọpaa Ọta-Ẹfun lọwọ fun iwadii kikun ati gbigbe lọ sile ẹjọ.
No comments:
Post a Comment