IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 10 April 2025

Lẹyin ọjọ mẹta to kuro lọgba awọn ajinigbe, oloye ẹgbẹ APC, Adekunle Adeniji, jade laye


Ọmọbibi ilu Ileefẹ nni, to tun jẹ alakoso eto gbogbo ninu ẹgbẹ oṣelu APC lorileede yii, Hon. Abdul-Raif Adekunle Adeniji, ti jade laye.


Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kinni ọdun yii ni wọn ji i gbe pẹlu awọn mẹta mi-in lagbegbe Chikakore, Kubwa ni Bwari Area Council niluu Abuja.


Lọjọ naa, wọn ji iyawo rẹ, ọmọ rẹ ọkunrin ati aburo rẹ kan, bẹẹ ni wọn pa iyawo aburo rẹ.


Nigba ti wọn gbọ pe oun ni alakoso fun eto gbogbo, Director for Administration fun ẹgbẹ oṣelu APC ni wọn beere fun miliọnu lọna ọtalelọọdunrun o din mẹwaa gẹgẹ bii owo itusilẹ rẹ.


Ọjọ Mọnde si Tusidee ọsẹ yii la gbọ pe wọn tu u silẹ lẹyin to lo ọsẹ bii mẹjọ lọdọ awọn ajinigbe, ti ko si sẹni to mọ iye ti wọn san fun itusilẹ rẹ.


Ṣugbọn aarọ yii niroyin gbalẹ pe ọkunrin naa ti jade laye, ti awọn olubanikẹdun si ti n lọ si ile ọkunrin naa niluu Ileefẹ bayii.

No comments:

Post a Comment