IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 12 April 2025

Iyansipo: Igbimọ Agba Ọṣun ba alaga ẹgbẹ APC dawọọdunnu


Lorukọ awọn Igbimọ Agba ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nipinlẹ Ọṣun, alaga wọn, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, ti fi idunnu wọn han si iyansipo Sooko Tajudeen Lawal gẹgẹ bii alaga igbimọ ajọ to n ri si iṣakoso ile-ẹkọ ijọba apapọ ti wọn ti n kọ nipa iṣẹ agbẹ, Federal College of Agriculture, niluu Ibadan.


Sooko Tajudeen Lawal, ọmọbibi ilu Ileefẹ, ni alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun lọwọlọwọ.


Akinwumi, ninu atẹjade kan to fọwọ si, dupẹ lọwọ aarẹ orileede yii, Oloye Bọla Hamed Tinubu, Oloye Bisi Akande ati minisita fun ọrọ igbokegbodo ọkọ loju omi, Alhaji Isiaka Adegboyega Oyetọla.


O ni ipa ribiribi lawọn eeyan naa ko lati ri i pe ika to tọ si imu ni wọn fi re e nitori ọlọpọlọ pipe ni Sooko Lawal, yoo si lo ọgbọn rẹ lati mu idagbasoke ba kọlẹẹji naa.


Igbimọ Agba Ọṣun wa gbadura pe ki asiko Lawal jẹ manigbagbe si rere nile-ẹkọ ọhun.

No comments:

Post a Comment