IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 2 April 2025

Ijamba ọkọ gbẹmi eeyan kan l'Ọṣun



Ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lagbegbe Onirin niluu Ileefẹ nipinlẹ Ọṣun ti gbẹmi ọkunrin kan bayii.


Adari ajọ ẹṣọ ojuupopo nipinlẹ Ọṣun, T. A. Ṣokunbi ṣalaye pe aago mẹsan ku iṣẹju mẹẹdogun aarọ ọjọ Wẹsidee ọjọ keji oṣu kẹrin ọdun yii niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.


Ṣokunbi ṣalaye pe mọto akoyọyọ alawọ funfun ti awọn ọmọkunrin meji wa ninu rẹ lo sọ ijanu nu, to si yọri si ijamba ọhun.


O sọ siwaju pe loju ẹsẹ ni ọkunrin kan ku, ti wọn si gbe e lọ sile igbokupamọ si nileewosan Obafemi Awolowo University, Ileefẹ, nigba ti ẹnikeji naa wa nibẹ fun itọju.


Ṣokunbi parọwa fun gbogbo awọn awakọ lati maa ri i daju pe mọto wọn wa ni ipo to dara ki wọn to gbe e sojuupopo.

No comments:

Post a Comment