IROYIN YAJOYAJO

Friday, 11 April 2025

Igbimọ Agba Ọṣun ṣedaro iku Dokita Rauf Adeniji 'Kongo'


Alaga Igbimọ Agba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Ọṣun, Ẹnjinia Sọla Akinwumi, ti ṣapejuwe iku alakoso fun eto gbogbo ninu ẹgbẹ oṣelu naa lorileede yii, Dokita Rauf Adekunle Adeniji, ti gbogbo eeyan mọ si Kongo, gẹgẹ bii adanu nla fun ẹgbẹ naa.


Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kinni ọdun yii ni awọn ajinigbe agbesunmọmi ji Kongo gbe pẹlu awọn mẹta mi-in lagbegbe Chikakore, Kubwa ni Bwari Area Council niluu Abuja.


Wọn beere miliọnu lọna ọtalelọọdunrun naira o din mewaa gẹgẹ bii owo itusilẹ, ṣugbọn lẹyin ti wọn gba owo to to miliọnu lọna aadọta naira ni ọkunrin naa tun ku sakata wọn.


Ẹnjinia Akinwumi sọ pe ọrọ bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n fojoojumọ padanu ẹmi wọn si ọwọ awọn ajinigbe agbesunmọmi yii ti waa di eyi to banilọkan jẹ pupọ.


Lorukọ Igbimọ Agba Ọṣun, Akinwumi ranṣẹ ibanikẹdun si aarẹ orileede yii, Bọla Hammed Tinubu, Oloye Bisi Akande, Alhaji Gboyega Oyetọla ati gbogbo awọn mọlẹbi ati ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lẹkajẹka.


Wọn gbadura pe ki Allah tẹ ọkunrin oloṣelu ọmọbibi ilu Ileefẹ naa si afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment