Ajọ kan ti ko rọgbọku lejọba, Ọlabọde Youth and Women Initiatives (OYAWIN) pẹlu ibaṣepọ AmplifyChange Pamoja Project, ti ṣedanilẹkọ ọlọjọ meji fun awọn oniroyin lori oniruuru ẹtọ ti awọn obinrin ni to ba kan ọrọ ibalopọ.
Nibi idanilẹkọọ naa, eyi to waye niluu Oṣogbo, ni alakoso agba fun OYAWIN, Comrade Moroof Ọlawale Ọlabọde, ti sọ pe bi awọn obinrin ṣe lẹtọọ si wiwa laaye naa ni wọn lẹtọọ lati pinnu iye ọmọ ti wọn fẹẹ bi pẹlu ẹnikeji wọn.
Gẹgẹ bo ṣe wi, 'Idanilẹkọọ ti a pe akori rẹ ni Advocacy on Sexual and Reproductive Health Rights, SRHR, fun awọn oniroyin yii wa lati le ṣi awọn obinrin lawujọ wa niye si awọn ẹtọ ti wọn ni labẹ ibalopọ.
'Fun ọpọ ọdun sẹyin la ti n sọ nipa awọn ilera to rọ mọ ibalopọ laarin awọn ọdọbinrin, idunnu wa ni yoo si jẹ ti awọn adari ilu ati awọn lamẹẹtọ awujọ ba n darapọ mọ wa lori ipolongo yii.
'Erongba wa ni lati mu idiwọ kuro lọna awọn ọdọbinrin atawọn obinrin agba lori awọn nnkan to yẹ ki wọn mọ nipa ibalopọ, ki wọn le gbe igbe aye alaafia gẹgẹ bii ti awọn ọkunrin''
Nibi idanilẹkọọ naa ni wọn ti sọ nipa oniruuru nnkan to le fa ifipabanilopọ; yala latọdọ ọkunrin tabi latọdọ obinrin, ati awọn ọna lati dena wọn.
Wọn sọ nipa awọn igbesẹ ti obinrin le gbe lati dena bibi ọmọ bii eku ẹda, ati ohun to yẹ ko jẹ ajọsọ laarin lọkọlaya ko too di pe ọrọ ibalopọ gan an fẹẹ ṣẹlẹ.
Pupọ awọn oniroyin ti wọn kopa nibi idanilẹkọ naa ni wọn ṣeleri lati tubọ maa la awọn araalu lọyẹ lori ẹtọ ti wọn ni nipa ibalopọ laarin obinrin ati ọkunrin.
No comments:
Post a Comment