IROYIN YAJOYAJO

Monday, 21 April 2025

Fungba keji, awọn janduku dana sun ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun, lawọn araalu ba ni ọrọ naa mu ifura lọwọ


Ọjọ kẹtala oṣu keji ọdun 2017 lawọn janduku kan ti kọkọ lọ dana sun ile ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Ọṣun to wa niluu Ileṣa, iyẹn Court 2, ti ijọba Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla si tun kootu naa kọ nigba naa.


Ṣugbọn iyalẹnu lo tun jẹ fawọn araalu nigba ti wọn gbọ pe wọn tun lọ dana sun kootu yii kannaa loru ọjọ Sannde mọjumọ Mọnde ọsẹ yii.


Agbẹnusọ fun Gomina Ademọla Adeleke, Mallam Ọlawale Rasheed ṣalaye pe ọpọlọpọ awọn iwe akọsilẹ atawọn nnkan ẹri (exhibits) ni wọn dana sun mọ inu kootu naa.


Adeleke ṣapejuwe iṣẹlẹ naa bi eyi ti ko bojumu, iwa ọdaran ati igbiyanju lati pagidina idajọ ododo.


Gomina wa paṣẹ pe ki awọn agbofinro bẹrẹ iwadii ni kia, ki wọn si ri i pe ọwọ tẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu iwa buburu naa.


Bakan naa lo paṣẹ pe ki ileeṣẹ to n ri si iṣẹ-ode ati ileeṣẹ eto idajọ ṣiṣẹ papọ lati tun kootu naa kọ.


Amọ ṣa, awọn lamẹẹtọ ilu ti ke gbajare bayii pe ijọba gbọdọ tuṣu desalẹ ikoko iṣẹlẹ naa nitori o ti n mu ifura lọwọ.


Wọn ni bawo lo ṣe jẹ pe Court 2 nikan ni awọn janduku n dana sun niluu Ileṣa? Wọn ni ki ẹka eto idajọ l'Ọṣun joko lati ṣayẹwo gbogbo ẹjọ to wa nibẹ atawọn to wa nidi ẹ.

No comments:

Post a Comment