IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 13 March 2025

Ti awọn ẹsun ti o fi kan mi ba da ẹ loju, gbe mi lọ siwaju ajọ EFCC ati ICPC - Alimi ta Banik laya


Kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ọṣun, Oluọmọ Kọlapọ Alimi ti ṣapejuwe kọmiṣanna tẹlẹ fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Ọmọọba Adebayọ Adeleke (Banik) gẹgẹ bii ajẹgbodo to n wẹni kunra.


O ni dipo ko tete yọnda ara rẹ fun ajọ to n gbogun ti lilu owo araalu ni ponpo lati sọ ipa to ko lori owo Ọṣun lasiko iṣejọba Alhaji Gboyega Oyetọla, atamọ-atamọ lo n wi kaakiri ori redio.

Alimi ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita pe oun i ba ti da Banik lohun lori ẹsun owo to din diẹ ni biliọnu mẹrin naira to sọ pe o dawati labẹ iṣakoso oun lasiko ti oun jẹ kọmiṣanna fọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, ṣugbọn oun ko fẹ ko fi ẹkọ tanna fawọn araalu lori ọrọ naa.

O ni oun ti fun awọn agbẹjọro oun laṣẹ lati wọ Banik lọ sile-ẹjọ lati le ṣalaye bi ọrọ owo ti oun ko mọdi naa ṣe kan oun, eleyii yoo si di ṣiṣe laipẹ nitori ẹsun ibanilorukọjẹ gbaa ni.

Alimi sọ siwaju pe dipo ki Banik sọ ọrọ naa di abata ninu eyi ti yoo maa wa awọn ti yoo dọti aṣọ wọn kaakiri, ṣe ni ko fori le ọdọ awọn ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorileede yii ati eyi to n digun mọ awọn to ba ṣe owo araalu baṣubaṣu ti awọn ẹsun naa ba da a loju.

O ni oun ṣetan lati dahun ipe ajọ kankan to ba pe oun nibikibi ti Banik ba mu awọn ẹsun to fi kan oun yii lọ.

O fi kun ọrọ rẹ pe oun gẹgẹ bii kọmiṣanna labẹ iṣejọba Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ko figba kankan lọwọ si ṣiṣe owo araalu kumọkumọ bii ti Banik to fi orukọ ileeṣẹ rẹ, Ice Farm Nig. Ltd gba iṣẹ eleyii to lodi si ofin ati ilana fun ẹnikẹni to ba di ipo mu.

Oluọmọ Alimi waa ke si Ọmọọba Adebayọ Adeleke lati dẹkun rirojọ kaakiri ileeṣẹ iroyin nitori ko si eyi to le gba a ninu ẹbiti ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu to ko si.

No comments:

Post a Comment