IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 8 March 2025

Oludije funpo gomina Ọṣun nigba kan ri, Ọjọgbọn Ọdẹyẹmi, jade laye


Ọkan pataki lara awọn ọmọbibi ilu Iloko Ijeṣa to tun ti figba kan ri dupoo gomina ipinlẹ Ọṣun, Ọjọgbọn Oluṣuyi Ọdẹyẹmi, ti jade laye.


Ọjọ Furaidee, iyẹn ọjọ keje oṣu kẹta ọdun yii la gbọ pe baba naa dagbere faye lẹni ọdun mọkandinlọgọrin.


Ọjọgbọn Ọḍẹyẹmi ni ọga agba akọkọ ni Osun State College of Technology, Ẹsa-Oke lọdun 1993 to si fi ipo naa silẹ lọdun 2000.


Oun ni aarẹ Ijesa Progressives Council ati alaga Iwude Ijesa Planning Committee. Oniruuru ami ẹyẹ ni oloogbe yii ti gba, o si fiyun lọlẹ gẹgẹ bii ọjọgbọn akọkọ to sọ igbọnṣe di gaasi.

No comments:

Post a Comment