Igun kan ninu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọṣun ti ke si gbogbo awọn akẹẹgbẹ wọn lati ṣaanu awọn araalu, ki wọn si pada sẹnu iṣẹ.
Igun naa, labẹ Association of Concerned Local Government Staff, sọ pe ohun ti ko bojumu ni bi awọn adari NULGE nipinlẹ Ọṣun ṣe dojuu gbogbo nnkan ru nijọba ibilẹ, ti gbogbo nnkan si duro daari latari ọrọ idajọ ile-ẹjọ kotẹmilọrun.
Alakoso wọn, Comrade Adedayọ Adekunle ati akọwe, Akin Adepọju, ṣalaye pe gbogbo ẹgbẹ oṣelu to ba wa nijọba ni NULGE maa n ba ṣiṣẹ, o si ku diẹ kaato bi aarẹ wọn l'Ọṣun, Dokita Nathaniel Ogungbangbe ṣe sọ ara rẹ di oloṣelu, lai ka ofin ẹgbẹ naa si nigba to kede pe ki awọn oṣiṣẹ joko sile.
Wọn ni oniruuru ifasẹyin lo ti ba ojuṣe awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ latigba ti Ogungbangbe ti paṣẹ pe ki wọn joko sile; awọn alaboyun ko lanfaani si itọju nileewosan, ko saaye fun igbeyawo nilana ofin to maa n waye ni sẹkiteriati, bẹẹ ni awọn ti wọn fẹẹ gba iwe isọmọlorukọ ko lanfaani si i.
Wọn sọ siwaju pe ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ ti asiko ifẹyinti wọn ti to ni wọn n kuro lẹnu iṣẹ lai si ayẹyẹ imọriri kankan, bẹẹ ni oju si n ti gbogbo awọn lati joko sile lai ṣiṣẹ.
Pẹlu bi ko ṣe lẹtọ fun oṣiṣẹ lati yan ẹgbẹ oṣelu kankan laayo, wọn ni Ogungbangbe darapọ mọ ẹgbẹ PDP lati gbe awọn alaga ẹgbẹ APC atawọn kanselọ wọn lọ sile ẹjọ.
Wọn ni Ogungbangbe le maa ṣe ẹjọ yẹn lọ, ṣugbọn ko lẹtọọ fun un lati tilẹkun sẹkiteriati lai bun awọn ẹgbẹ yooku gbọ.
Adedayọ waa ke si awọn oṣiṣẹ pe eto aabo to peye ti wa fun ẹmi wọn kaakiri sẹkiteriati l'Ọṣun, ki wọn pada sẹnu iṣẹ ti wọn gba wọn fun nitori ọlẹ lo maa n gbowo oṣu lai ṣiṣẹ.
No comments:
Post a Comment