IROYIN YAJOYAJO

Monday, 24 March 2025

O ma ṣe o! Ijamba ọkọ gbẹmi akẹkọọ UNIOSUN marun


Akẹkọọ Fasiti Ọṣun marun-un ni wọn kagbako iku ojiji nitosi Unity School lagbegbe Balogun niluu Ikire lọjọ Sannde to kọja, iyẹn ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta ọdun yii.


Mọto akero nla kan, Luxurious Bus, to n bọ lati ọna Ibadan lo fori sọ mọto bọọsi elero mejilelogun to n bọ lati Oṣogbo ti awọn akẹkọọ yii wa ninu ẹ.

Ṣe ni bọọsi gigun ọhun gba 'one way' eleyii to ṣokunfa ijamba to gbẹmi Ọlagbemide Dọtun, (200-level student of Software Engineering), Suleiman Farouq Adedayọ, (400-level student of Law), Ogundare Pẹlumi, (300-level student of Public Health), Ogundare Elijah, (100-level student of Mechanical Engineering) ati Ọlawuyi Mary, (200-level student of Nursing)

Alukoro Fasiti naa, Ademọla Adesọji ṣalaye pe akẹkọọ miran, Ọlagbemide Damilọla farapa ninu ijamba naa, o si n gba itọju lọwọ nileewosan.

Adesọji ṣalaye pe ajalu niṣẹlẹ naa jẹ fun awọn alaṣẹ, oṣiṣẹ atawọn akẹkọọ Fasiti naa. O ni awọn alakoso yoo ṣabẹwo sọdọ awọn idile awọn akẹkọọ ọhun lati ba wọn kẹdun ati lati duro ti wọn lorii gbogbo eto isinku awọn ẹniiwọn to lọ.


No comments:

Post a Comment