Comrade Nathaniel Kehinde Ogungbangbe ni wọn ti kede gẹgẹ bii aarẹ agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ lorileede yii ẹka tipinlẹ Ọṣun.
Nibi eto idibo to waye ni Western Sun niluu Ẹdẹ lọjọ Tusidee, ọjọ kẹrin oṣu kẹta ọdun 2025 ni Ogungbangbe ti jawe olubori laarin awọn mẹrin ti wọn jọ dupo naa.
Awọn yooku ti wọn tun dibo yan niwọnyii:
Olanrewaju Fatima Iyabo as Deputy State President
Rafiu Kabiru as State Young Worker
Olayanju Israel as State Welfare Officer
Owoeye David as State Publicity Secretary
Adepoju Taofeeq Olalekan as State Treasurer
Ogunkanmi Oluwatoyin as Women Chairperson Committee
Adewoyin Olatilewa as State Trustee
Com Onikola Kayode Akeem as State welfare officer
Com Aderanti Samuel as State Welfare Officer
Com Olukitibi Akinola Matthew as State Auditor
Com Abiona Rafiu as State Auditor
Com Azeez Musefiu Alani as State Trustee.
Ninu ọrọ rẹ, Ogungbangbe dupẹ lọwọ awọn akẹẹgbẹ rẹ ti wọn dibo yan an fun saa keji, o si ṣeleri pe oun ko nii ja wọn kulẹ.
O pe fun ifọwọsowọpọ siwaju sii, bẹẹ lo fi da wọn loju pe igbayegbadun wọn yoo tun ṣe pataki si oun ni saa keji yii gẹgẹ bi oun ṣe ṣe ni saa akọkọ.
No comments:
Post a Comment