Ajọ to n ṣeto idibo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọṣun, Osun State Independent Electoral Commission (OSSIEC) ti fi da gbogbo awọn ojulowo oṣiṣẹ ti wọn lo lasiko idibo ọjọ kejilelogun oṣu keji ọdun yii loju pe laipẹ yii ni wọn yoo gba owo iṣẹ wọn.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ajọ naa, Sadiat Isiaka, fi sita lorukọ alaga wọn, Amofin Hashim Abioye, lo ti ṣalaye pe loootọ ni OSSIEC jẹ awọn oṣiṣẹ naa lowo, ṣugbọn afikun latọdọ awọn alatako ni owo nla ti wọn n pariwo kaakiri pe wọn jẹ wọn.
Abioye tẹ siwaju pe gbogbo awọn ti wọn ṣedanilẹkọ fun ṣaaju idibo ati awọn ti wọn lo lọjọ idibo ni wọn yoo gba owo wọn.
'OSSIEC ko jẹ ẹnikẹni ni owo to to biliọnu kan ataabọ naira, iroyin ẹlẹjẹ lati le ba orukọ ajọ wa jẹ ni. Bi awọn ọlọpaa ṣe kogun ti ajọ wa, ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo lo fa idaduro ninuu sisan owo wọn.
'Tẹ o ba gbagbe, awọn ọlọpaa ti ọfiisi wa pa patapata. A koo tii pada daadaa sẹnu iṣẹ latigba ti a ti pari idibo yii. Awọn oṣiṣẹ ti a mu fun idanilẹkọọ atawọn ti a lo lọjọ idibo yoo gba owo wọn. A ti sọ fun wọn, wọn si mọ ohun ti a n doju kọ lọwọlọwọ.
'A ko tii pada si ọfiisi lati ṣe ohun gbogbo to yẹ ka ṣe lati le yanju owo wọn, ṣugbọn laipẹ rara, wọn yoo ri owo wọn gba'
No comments:
Post a Comment