IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 19 March 2025

Ikede ijọba pajawiri: Ageku ejo ni Ajibọla Baṣiru atawọn ọmọ ẹgbẹ APC, ṣe ni wọn n retii ki wahala ṣẹlẹ l'Ọṣun - Alimi


Kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ọṣun, Oluọmọ Kọlapọ Alimi ti bu ẹnu atẹ lu akọwe apapọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, lorileede yii, Sẹnetọ Ajibọla Baṣiru lori ọrọ kan to sọ laipẹ yii pe ṣe ni ki Aarẹ Bọla Tinubu kede ijọba pajawiri nipinlẹ Ọṣun gẹgẹ bo ṣe ṣe nipinlẹ Rivers.


Alimi, ninu atẹjade kan to fi sita, ṣalaye pe iwa ẹni to jẹ ika, onimọ-taraẹni nikan ati alaibọwọ fun ofin ni Baṣiru hu pẹlu ọrọ to sọ naa nitori ohun to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ nipinlẹ Rivers yatọ gedengbe si nnkan to n ṣẹlẹ nipinlẹ Ọṣun.


O gba Ajibọla nimọran lati dẹkun iwa to le da omi alaafia ipinlẹ Ọṣun ru latari bi oun atawọn ọmọ ẹgbẹ APC ṣe n fojoojumọ wa ọna alumọkọrọyin lati pada sijọba, eleyii ti Ọlọrun atawọn araalu ko nii fun wọn laaye lati ṣe.


Alimi ke si Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lati ri Ajibọla Baṣiru atawọn ọmọ ẹgbẹ APC ti awọn araalu ti kọ̀ gẹgẹ bii ageku ejo to n japoro kaakiri, ko si de fila mawobẹ si ariwo ikede ijọba pajawiri ti wọn n pa kaakiri.


O sọ siwaju pe ẹgbẹ APC Ọṣun mọ pe awọn ko kaju ẹ lati ba Gomina Ademọla Adeleke forigbari ninu idibo kankan, idi niyẹn ti wọn ṣaa fi n wa gbogbo ọna lati da wahala silẹ nipasẹ eyi ti wọn yoo fi gbọna ẹburu dejọba, ọkan lara awọn ọna naa si ni iru wahala ti wọn da silẹ lori idajọ ile-ẹjọ kotẹmilọrun ti wọn sọ pe o ni ki awọn alaga ẹgbẹ awọn pada si sẹkiteriati.


Alimi ni Adeleke ti fura ọgbọn arekereke wọn lo ṣe paṣẹ pe awọn alaga ti wọn wọle ibo loṣu keji ọdun yii ko gbọdọ lọ si sẹkiteriati, lai ṣe bẹẹ, rogbodiyan nla i ba ti bẹ silẹ l'Ọṣun.


O ni ẹjọ mẹta ọtọọtọ lo wa nile ẹjọ bayii lorii ohun to n ṣẹlẹ l'Ọṣun nitori ọrọ lori ofin ni, ile-ẹjọ naa ni yoo si yanju ẹ, ki i ṣe ọrọ ikede ijọba pajawiri.

No comments:

Post a Comment