Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti fi da awọn araalu loju pe ijọba oun ko nii yẹsẹ ninu ipinnu rẹ lati maṣe ya owo kankan fun iṣẹ akanṣe ti wọn ba n ṣe.
Lasiko ti gomina n ṣi aṣọ lorii awọn iṣẹ akanṣe ti owo rẹ din diẹ ni biliọọnu lọna ọgọjọ naira, iyẹn #159.1b, tijọba rẹ fẹẹ ṣe lọdun yii lo ṣalaye pe ẹka mẹta lawọn yoo doju kọ lọdun yii.
Adeleke sọ siwaju pe ijọba yoo mojuto eto ẹkọ, eto ilera ati iṣẹ-ode, iyẹn atunṣe awọn oju-ọna lọdun un 2025, ti gbogbo rẹ yoo si laṣeyọri gẹgẹ bo ṣe ṣẹlẹ lọdun un 2024.
Lara awọn ilu tijọba yoo ti ṣe awọn iṣẹ akanṣe oju-ọna ni ilu Ejigbo, Iwo, Iragberi, Ẹdẹ, Ijẹbujeṣa, Ibokun, Ilaṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, owo to si le ni biliọnu lọna ọgọrun naira ni wọn yoo na lori wọn.
Ni ti eto ẹkọ, ijọba yoo de awọn ilu bii Ileefẹ, Ẹdẹ, Ileṣa Ikire, Iwo, Iragbiji ati Oṣogbo, owo to din diẹ ni biliọnu meji naira ni wọn yoo na le e lori.
Gbogbo awọn ileewosan alabọọde mẹrinlelọgọfa ti wọn ko tii ṣatunṣe wọn ni gomina sọ pe ijọba yoo tun ṣe pẹlu owo to din diẹ ni biliọnu mẹta naira.
Adeleke tẹ siwaju pe ko si aaye ina-apa kankan, bẹẹ nijọba yoo mojuto owo to n wọle labẹnu nipasẹ ṣiṣe iṣẹ papọ pẹlu awọn olokoowo abẹle.
Lara awọn ti wọn wa nibi eto naa ni igbakeji gomina, Ọmọọba Kọla Adewusi, akọwe ijọba, Bọbagunwa Teslim Igbalaye, abẹnugan ile igbimọ aṣofin, Honourable Adewale Ẹgbẹdun.
No comments:
Post a Comment