Minisita fun ọrọ okoowo lori omi lorileede Naijiria, Alhaji Gboyega Oyetọla ti ṣalaye pe ohun kanṣoṣo to le mu inu iya oun dun ni ọrun to wa bayii ni ki oun kọ mọṣalaaṣi lorukọ jẹ.
O ni gbogbo aye iya oun to jẹ Iyalaje Adinni lo fi sin Allah titi di ọdun mẹrinla sẹyin to jade laye.
Nibi ayẹyẹ ṣiṣi Alhaja Wulemọtu Arikẹ Oyetọla Memorial Central Mosque to wa niluu Iragbiji lọjọọ Furaidee, ọjọ keje oṣu kẹta ọdun yii ni Oyetọla ti sọ pe, ti iya oun ba wa laye ni, ohun idunnu nla ni igbesẹ naa i ba jẹ fun un.
O ni lati ọdun meji sẹyin lo ti wa lọkan oun lati kọ mọṣalaaṣi naa fun mama oun nitori 'lọdun un 2006 ti mọṣalaaṣi nla kan fi iya mi jẹ Iyalaje Adinni, mo beere pe ki ni wọn fẹ ki n ṣe fun awọn, mama mi ni ki n pe awọn ọrẹ mi jọ lati tun mọṣalaaṣi naa ṣe.
'A ko miliọnu mẹfa ataabọ naira jọ nigba naa, a si lo gbogbo rẹ lati fi ṣatunṣe mọṣalaaṣi yẹn. Mo wa ro o pe ki lo le jẹ idunnu mama mi ti wọn ba wa laye, mo wa pinnu pe yoo dara ti mo ba kọ mọṣalaaṣi apapọ kan niranti wọn'
Ninu ọrọ Aṣiwaju Musulumi ilẹ Yoruba, Edo ati Delta, Alhaji Khamiz Badmus, o ni ohun ti Oyetọla ṣe yii gbọdọ jẹ awọkọṣe rere fun gbogbo musulumi ododo.
O ni Alhaja Wulemọtu Oyetọla ko fẹ nnkan kan funraa rẹ ju ohun ti yoo jẹ manigbagbe lẹyin rẹ lọ, eleyii ti yoo si jogun ni alujanna. O rọ gbogbo ẹlẹsin Islam lati sa fun iwa imọtaraẹni nikan.
Bakan naa ni Sheikh Imran Ẹlẹha ṣalaye pe ohun gbogbo ti polukumuṣu ni iran ti a wa yii, idi niyẹn ti mọṣalaaṣi fi gbọdọ pada si ojuṣe kikọni lẹkọọ to ye kooro dipo bo ṣe jẹ adura nikan lo ku ti wọn n gba.
O ni ti awọn mọṣalaaṣi ko ba tete pada sinu awọn ojuṣe yii, satani a maa jẹ gaba lori awujọ wa, awọn iwa buburu a si maa fojoojumọ gbilẹ si i.
Lara awọn eeyan jankanjankan ti wọn tun wa nibi ayẹyẹ naa ni Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi, Aragbiji ti ilu Iragbiji, Ọba Ọlabomi, Alhaja Kafayat Oyetọla, Aṣiwaju Bọla Oyebamiji ati iyawo rẹ, Hon. Yekeen Adeleke (Banik), Oloye Abiọla Ogundokun, Ẹnjinia Ọlalekan Badmus, Hon. Kayọde Oduoye, Ọmọọba Dọtun Babayẹmi, Alhaji Kazeem Adio, Hon. Taiwo Oluga, Hon. Ọmọlaoye, Hon. Oyintiloye, Hon. Jamiu Ọlawumi, Hon. Babatunde Ayẹni ati bẹẹ bẹẹ lọ.
No comments:
Post a Comment