Gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ Ọṣun ti wọn kopa ninu idanwo tijọba ṣeto rẹ lati gba awọn olukọ sileewe alakọbẹrẹ ati girama, ti wọn si ṣaṣeyege ni Gomina Ademọla Adeleke ti paṣẹ pe ki wọn bẹrẹ sii fun ni lẹta bayii.
Tẹ o ba gbagbe, lẹyin tawọn eeyan naa ṣedanwo alakọsilẹ lọdun to kọja ni awọn ti wọn yege tun ṣe ayẹwo, latigba naa si lẹnikan ko ti gbọ nnkan kan mọ nipa rẹ.
Amọ ṣa, ninu ipade awọn igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Ọṣun to waye lọjọọ Mọnde, ọjọ kẹwaa oṣu kẹta ni gomina ti paṣẹ pe ki ileeṣẹ tọrọ kan bẹrẹ sii pin lẹta igbaniṣiṣẹ fun wọn kiakia.
Adeleke ṣalaye pe oṣu nla ni oṣu keji jẹ funpinlẹ Ọṣun, wahala si pọ lọtunlosi, ṣugbọn ohun gbogbo ti pada bọ sipo bayii.
O ṣeleri pe oun ko nii kaarẹ ninuu pipese ijọba to duroore fawọn ọmọ ipinlẹ Ọṣun lai fi ti ipenija latọdọ awọn alatako oun ṣe rara.
No comments:
Post a Comment