IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 22 March 2025

Eyi lohun ti maa ṣe fawọn ọba ilu mẹtẹẹta ti mo ba tun gburo wahala ni Ifọn, Ilobu ati Ẹrin Ọṣun - Adeleke ṣekilọ


Gomina Ademọla Adeleke ti kilọ pe ṣe loun yoo paṣẹ pe ki awọn ọba ilu Ifọn, Ilobu ati Ẹrin Ọṣun lọọ rọọkun nile ti wahala kankan ba tun ṣẹlẹ lagbegbe wọn.


Lasiko ti gomina n ṣepade pẹlu awọn ọga ileeṣẹ agbofinro nipinlẹ Ọṣun, awọn ọba ilu mẹtẹẹta atawọn lookọlookọ lati awọn ilu naa lọjọ Satide ọjọ kejilelogun oṣu kẹta ọdun yii lo ṣekilọ yii.

Adeleke ni wahala naa ti n di lemọlemọ bii ẹkun apọkọjẹ, oun ko si fẹ ogun mọ laarin awọn ilu mẹtẹẹta nitori naa awọn ọba yii gbọdọ lọ ba awọn ọmọ ilu wọn sọrọ lato so ewe agbejẹ mọwọ.

O paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ alaabo lati pe gbogbo awọn abẹnugan ninu ilu mẹtẹẹta sagọọ wọn lati tọwọ bọwe alaafia, ki wọn si mọ pe awọn n fi ẹwọn ṣere ti wahala kankan ba tun ṣẹlẹ.

Bakan naa lo ni ki wọn fi panpẹ ofin mu ẹnikẹni to ba n lo ikanni ayelujara lati konaa wahala nipasẹ gbigbe iroyin ẹlẹjẹ tabi fidio atijọ kiri.

No comments:

Post a Comment