Ọba Ọlayinka Gbọlagade Tiamiyu 11, Olojo ti ilu Ojo nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ nipinlẹ Ọṣun ti darapọ mọ awọn babanla rẹ.
Ọjọ kejilelogun oṣu kọkanla ọdun 1946 ni wọn bi Ọba Gbọlagade nidile ọlọmọọba Onimọlọdun niluu Ojo.
Kabiesi ni oludasilẹ ileeṣẹ bureḍi Oluwalomọṣe niluu Ejigbo, to si ni ẹka niluu Ilobu ati Ojo.
O gun ori-itẹ awọn babanla rẹ lẹyin ti ọba ijẹta, Ọba Samuel Ọmọtọshọ waja lọdun un 1991.
No comments:
Post a Comment