Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nipinlẹ Ọṣun ti dunkoko pe awọn yoo kọ orukọ gbogbo awọn lookọlookọ ninu ẹgbẹ naa kaakiri orileede yii ti wọn n fẹnu tẹmbẹlu ẹgbẹ ọhun l'Abuja nitori ibaṣepọ wọn pẹlu Gomina Ademọla Adeleke jade faraye ri laipẹ.
Ninu atẹjade kan ti alakoso eto iroyin wọn, Mọgaji Kọla Ọlabisi, fi sita ni wọn ti sọ pe o jẹ ohun ti ko ṣetẹwọgba bi awọn kan ṣe n lọ sọdọ Aarẹ Tinubu lati gbe Adeleke kalẹ gẹgẹ bii eeyan daadaa, ti wọn si n sọ oniruuru nnkan ti ko dara nipa ẹgbẹ APC l'Ọṣun.
Atẹjade naa ṣalaye pe, 'Eti wa ti kun fun oniruuru ipa aitọ ti awọn lookọlookọ kan ninu ẹgbẹ wa lati awọn ipinlẹ ti ẹgbẹ wa n ṣakoso ati awọn ti wọn n ṣiṣẹ pẹlu aarẹ to yẹ ki wọn maa fọnrere ohun to dara nipa ẹgbẹ wa n ko lati faaye gba Gomina Adeleke l'Abuja.
'Koda, a ti ni akọsilẹ orukọ awọn eeyan ti wọn ko fẹ ire ẹgbẹ wa yii, gomina wa lara wọn, bẹẹ ni awọn minisita kọọkan wa lara wọn, to jẹ pe nitori okoowo to wa laarin awọn ati Gomina Adeleke ni wọn ṣe n ṣeto aaye fun un lọdọ aarẹ.
'A mọ pe a ko le yan ọrẹ fun ẹnikẹni, ṣugbọn a n kilọ fun gbogbo awọn afojufẹni-ma fọkanfẹni yii lati jawọ lọrọ wa ko too di pe a maa kede orukọ wọn faraye gẹgẹ bii ọta ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun.
'Ko si ohun to yẹ ko jẹ idi pataki fun ẹnikẹni lati ṣọrẹ pẹluu gomina to huwa to yọri si iku alaga ijọba ibilẹ Irewọle, Remi Abass, ẹni ti wọn pa ni ipa ailaanu ni sẹkiteriati rẹ laipẹ yii, to si tun jẹ pe aimọye ọmọ ẹgbẹ wa lawọn janduuku ẹgbẹ PDP pa lati le jẹ ki Adeleke atawọn aṣofin wọn wọle ibo laarin ọdun 2022 si 2023.
'A fẹ sọ gbangba fun ileeṣẹ aarẹ pe digbi ni ẹgbẹ APC wa l'Ọṣun, koda, Gomina Adeleke mọ pe nnkan ṣe oun. Ohun ti a ko le faramọ ni ki awọn alarekereke kan maa ṣafihan Gomina Adeleke bii ọmọ gidi lọdọ Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu nigba to wa ninu akọsilẹ pe aimọye igba ni Adeleke ti sọrọ kobakungbe si aarẹ lai nidi.
'Ki i ṣe asọdun pe nipasẹ idari gomina ana l'Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, alaga ẹgbẹ APC, Sooko Tajudeen Lawal ati itọsọna Agba Ọṣun labẹẹ Ẹnjinia Sọla Akinwumi, idaamu ti ba ẹgbẹ PDP, eleyii ti yoo si wa bẹẹ titi di ọdun 2026 ti a fi maa le Gomina Adeleke kuro ni Bọla Ige House nipasẹ ibo wa''.
No comments:
Post a Comment