Mo ti gbọ nipa ọrọ kan ti wọn ni Amofin Kọlapọ Alimi to jẹ kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ Ọṣun sọ pe oun yoo pe mi lẹjọ lori ẹsun ṣiṣe owo to din diẹ ni biliọnu mẹrin naira baṣubaṣu lasiko to jẹ kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ lọdun 2017.
Mo pe Amofin Alimi nija lati ṣafihan bi owo nla yii ṣe dawati ninu akanti ALGON labẹ iṣakoso rẹ fun gbogbo aye lai si iṣe kankan ti wọn le tọka si pe wọn fi owo naa ṣe. Gẹgẹ bii kọmiṣanna, ojuṣe rẹ ni lati mojuto bi wọn ṣe n nawo, bo tilẹ jẹ pe ko si lara awọn to le buwọ lu akanti naa.
Akọsilẹ fi han pe ko si ẹri kankan lorii bi wọn ṣe lo #3.7bilion, bẹẹ ni ko si akọsilẹ iṣẹ akanṣe ti wọn fi ṣe. Gẹgẹ bii ẹni to gbaṣẹ lọwọ rẹ nileeṣẹ yii, mo ri i daju pe gbogbo iṣẹ akanṣe ati eto inawo wa lakọsilẹ yekeyeke, bẹẹ ni ayẹwe-owo wo funjọba ibilẹ fọwọ si i.
Mo rọ Amofin Alimi lati mu ẹri jade nipa iṣẹ iriju rẹ gẹgẹ bii kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ laarin ọdun 2017 si 2018 gẹgẹ bi emi ṣe ṣe ninu atẹjade nla kan ti ayẹwe-owo wo funjọba ibilẹ lu lontẹ.
Eleyii yoo fun awọn araalu lanfaani lati dajọ bo ti tọ.
O jẹ nnkan ti ko ṣetẹwọgba fun Amofin Alimi lati maa fi ọrọ kootu dunkoko mọ iru emi nigba to kuna lati sọrọ lori ẹsun ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu labẹ akoso rẹ. Iwa itiju ti ko yẹ ẹni to ba dipo mu lo hu yii.
Mo fẹ ko mọ pe gbankọgbi ọrọ ṣi n bọ lorii rẹ, mo si fẹ ko mura silẹ lati lọ si kootu lai mọye igba.
Mo fẹẹ beere awọn ibeere yii lọwọ Alimi:
1. Ṣe owo le wọnuu akanti ALGON lati JACC lai ṣe pe gomina fọwọ si i tabi wọn fọwọ si i lati ipade JACC?
2. Ṣe ko si lẹta lati ọfiisi rẹ gẹgẹ bii kọmiṣanna si gomina lati gba aṣẹ lori awọn iṣẹ akanṣe bẹẹ latọdọ ALGON ?
3. Ṣe ko yẹ ki o mọ iṣẹ akanṣe ti ALGON fẹẹ ṣe ko too di pe o tiransifaa owo si akanti rẹ̀?
4. Ṣe ki i ṣe ojuṣe rẹ ni lati mojuto iru awọn iṣẹ akanṣe bẹẹ lati ri i pe wọn ṣe e daadaa?
5. Mo ti ṣalaye, pẹlu ẹri aridaju ati ọpọ aworan fun gbogbo aye, nnkan ti ALGON, labẹ idarii temi lo owo ti o fẹsun kan wọn pe wọn ṣe baṣubaṣu tabi wọn ji ṣe. Iwọ naa jade sita ṣeru ẹ dipo irọ ati ẹkun ti o n sun kaakiri.
6. Ọpọlọpọ lo ṣi n bọ o. Jọwọ, mura silẹ lati lọ si Ile-ẹjọ Agbaye, International Court of Justice ni Hague.
7. O ni lati ṣalaye fun gbogbo awọn eeyan Ọṣun lorii bi #3.7Bilion ṣe huyẹ, to si fo lakanti ALGON labẹ iṣakoso rẹ lai si ẹri iṣẹ ti wọn fi ṣe.
8. Akanti banki miran tun tu aṣiri pe wọn gba miliọnu lọna irinwo naira jade ninu akanti ALGON lọjọ kan ṣoṣo lai si ẹri iṣẹ ti wọn fi ṣe.
No comments:
Post a Comment