IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 13 February 2025

Yiyọ ẹkun mi, bii ti ojo kọ o - Adeleke kilọ fun awọn adaluru l'Ọṣun


Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti kilọ pe gbogbo agbara to wa nikawọ oun loun yoo lo lati ri i pe ko si aaye fun ẹnikẹni lati da wahala silẹ nipinlẹ naa.


Lasiko to n lọọgun fun awọn araalu lorii aṣiri erongba awọn adaluru kan ti wọn fẹẹ da wahala silẹ kaakiri awọn sẹkiteriati ijọba ibilẹ to wa l'Ọṣun to tu sijọba lọwọ ni Adeleke kilọ pe didakẹ oun ki i ṣe pe oun n ṣojo rara.

Yatọ si awọn sẹkiteriati, atẹjade latọdọ agbẹnusọ fun Adeleke, Mallam Ọlawale Rasheed, tun fidi rẹ mulẹ pe awọn janduku yii tun fẹẹ ṣekọlu si awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) atawọn abẹṣinkawọ gomina.

O ni erongba awọn eeyan yii ni lati da rukerudo silẹ kaakiri ipinlẹ Ọṣun, ki eto idibo ijọba ibilẹ to n bọ lọna ma baa waye. O ni ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ yoo fimu kata ofin.

Gomina, ẹni to ṣapejuwe ipinlẹ Ọṣun gẹgẹ bii ipinlẹ ti alaafia ti n jọba julọ lorileede Naijiria, gboju aagan si bi ẹgbẹ APC ṣe n mu atamọ mọ atamọ lati dori idajọ ile-ẹjọ kodo dipo ki wọn gbajumọ igbaradi fun eto idibo ọjọ kejilelogun oṣu keji ọdun yii.

O sọ siwaju pe idajọ kan wa ti ẹgbẹ APP gba, eleyii to fagile idibo ijọba ibilẹ to waye lọdun 2022, nigba ti ti ile-ẹjọ kotẹmilọrun l'Akurẹ da lorii ọna ti ẹgbẹ PDP gba pe ẹjọ, eyi ti ko ni nnkan kan ṣe pẹlu eyi ti ẹgbẹ APP ti kọkọ gba.

“Mo ti fun awọn ẹṣọ alaabo ni aṣẹ lati fi pampẹ ofin gbe ẹni to ba huwa ọmọ ganfe. Ko si idajọ kankan to ni ki ẹnikẹni lọọ gbakoso ijọba ibilẹ l'Ọṣun. Idibo lati yan alaga ati kanselọ yoo waye lọjọ kejilelogun oṣu keji ti a wa yii''

Gẹgẹ bii aṣaaju ikọ alaabo nipinlẹ Ọṣun, Gomina Adeleke kilọ pe ẹnikẹni to ba da wahala silẹ yoo da ara rẹ lẹbi. O si ke si awọn araalu lati maa ba iṣẹ wọn lọ lai bẹru tabi ṣojo rara.

No comments:

Post a Comment