..Eeyan mẹrin ku, ọlọpaa meje farapa
Latigba diẹ sẹyin ni ilu Ẹsa-Oke ati Ido-Ijeṣa ti ni gbolohun asọ lori ọrọ ẹni to lagbara lori agbegbe Ido-Ajegunlẹ nijọba ibilẹ Obokun nipinlẹ Ọṣun.
Ohun ti a gbọ ni pe Ọwamiran ti ilu Ẹsa-Oke lo maa n fi baalẹ jẹ ni Ido-Ajegunlẹ, koda, oun lo fi eyi to wa nibẹ lọwọlọwọ, Oloye Ọpẹyẹmi Ogunṣijj, jẹ lọdun meje sẹyin.
Ṣugbọn lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kin-in-ni ọdun yii ni igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Ọṣun kede pe Ido-Ajegunlẹ di ọlọba, wọn si fọwọ si yiyan Ọmọọba Timilẹyin Oluyẹmi Ajayi to wa lati orileede Amẹrika gẹgẹ bii Olojudo ti Ido-Ajegunlẹ.
Eleyii lo di wahala, ti awọn ọdọ Ido-Ajegunlẹ fariga pe ọmọbibi ilu Ileṣa nijọba yan le awọn lori dipoo ki wọn sọ baalẹ awọn di ọba.
Gbagede gbọ pe awọn ọdọ kan ti wọn jẹ alatilẹyin ọba tuntun yii kora jọ lọjọ Sannde, ọjọ keji oṣu keji ọdun yii, wọn si da ayẹyẹ ifinijoye obinrin kan ti Oloye Ọpẹyẹmi Ogunṣiji fẹẹ fi jẹ ru, ṣugbọn awọn ọdọ ilu dojukọ wọn, wọn si fa diẹ lara wọn le awọn ọlọpaa lọwọ.
Lalẹ ọjọ Sannde yii lawọn kan lọọ ji Oloye Ogunṣiji gbe laafin rẹ, ko si sẹni to mọ ibi to wa titi di asiko yii.
Idaji ọjọ Mọnde, ọjọ kẹta oṣu keji ni wahala bu rẹkẹ, nigba ti awọn ọdọ koju awọn ọlọpaa, ti ibọn si n ro lakọlakọ labala mejeeji.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe ọlọpaa meje lo farapa lasiko ti awọn ọdọ doju ija kọ wọn.
Ninu ọrọ tirẹ, Ọladiti Awodiran, aṣoju fun Ẹsa-Oke Descendants Union, ṣalaye pe o kere tan, eeyan mẹrin lawọn gbọ pe o ti ku, ti ọpọ si farapa, wọn dana sun mọto Ọwamiran mẹta, ti gbogbo nnkan ko si fararo ninu ilu naa bayii.
No comments:
Post a Comment