IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 26 February 2025

TOM di ẹbi rogbodiyan nipinlẹ Ọṣun ru ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP


The Osun Mastermind (TOM) ti sọ pe gbogbo rogbodiyan to ṣẹlẹ nitori idibo ijọba ibilẹ to waye kọja nipinlẹ Ọṣun ko ṣẹyin imọtara-ẹni nikan to wa ninu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ati Peoples Democratic Party (PDP).


TOM ni to ba jẹ pe ẹgbẹ oṣelu mejeeji ni ifẹ awọn araalu lọkan ni, ti wọn si mọ pe ibi ti erin meji ba ti ja, koriko ibẹ ni yoo jiya ju, wọn i ba lo ọna ofin dipo ọna ifẹ inu ara ẹni lati yanju ọrọ naa.

Alakoso TOM, Ọjọgbọn Wasiu Oyedokun-Alli, ṣalaye nibi ipade oniroyin oloṣooṣu ti wọn maa n ṣe pe niwọn igba ti ile-ẹjọ kotẹmilọrun ti gbe idajọ kalẹ, ti ko si sẹni to fẹẹ gba abala pe oun jẹbi, ṣe lo yẹ kawọn mejeeji pada si kootu lati beere itumọ to peye fun idajọ naa.

O ṣalaye pe dipo bi awọn mejeeji ṣe bẹrẹ ifigagbaga nipasẹ eyi ti ọpọ ẹmi ati dukia ṣofo, ṣe lo yẹ ki wọn bọwọ fun ilana ofin, ki wọn si beere itumo tọ tọ fun idajọ ọhun.

TOM sọ siwaju pe eyi to buru ju ni bi alaga ajọ OSSIEC to jẹ amofin, Hassim Abioye, ṣe faake kọri lati ṣeto idibo naa lai naani ohun ti ile-ẹjọ sọ, eleyii to si mu ifura dani.

O ni ai ni arojinlẹ lo fa a ti Abioye fi gbe igbesẹ naa nitori ko si nnkan to buru nibẹ bo ba da eto idibo naa duro fungba diẹ lati le mọ ohun ti kootu n sọ gan an.

TOM sọ siwaju pe bi awọn oṣisẹ ijọba ko ṣe ṣiṣẹ ni sẹkiteriati ijọba ibilẹ n sạkoba pupọ fun eto ọrọ-aje ipinlẹ Ọṣun nitori ijọba to sunmọ araalu ju niyẹn, o si rọ wọn lati maṣe sọ ara wọn di irinṣẹ lọwọ awọn oloṣelu.

No comments:

Post a Comment