IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 16 February 2025

Tinubu, kilọ fun Oyetọla ko too da wahala silẹ l'Ọṣun o - Adeleke ke gbajare


Gomina Ademọla Adeleke ti ke si Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lati kilọ fun minisita fun ọrọ okoowo ori omi, Alhaji Gboyega Oyetọla lati maṣe da wahala silẹ nipinlẹ Ọṣun.


Nibi ipade oniroyin ti Adeleke ṣe lo ti sọ pe ṣe ni Oyetọla, ẹni to jẹ gomina ana l'Ọṣun fẹẹ lo ọrọ idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun nipa awọn alaga ijọba ibilẹ lati fa aibalẹ aya fawọn araalu.

O ni orukọ Aarẹ Tinubu ni Oyetọla n da, to si jẹ pe ọdọ rẹ lawọn agbofinro ti n gba aṣẹ bayii, eleyii to le yọri si iṣekupa awọn araalu.

Adeleke fi kun ọrọ rẹ pe oun ko tii di gomina lasiko ti kootu yọ awọn alaga ati kanselọ ẹgbẹ APC lọdun 2022, ko si si idajọ kankan to fun wọn lagbara lati pada si sẹkiteriati bayii.

O ni, gẹgẹ bii aarẹ to nigbagbọ ninu idajọ ododo, oun mọ pe Aarẹ Tinubu ko nii fun Oyetọla ni iru aṣẹ bẹẹ, adaṣe iṣẹ lo n jẹ.

Adeleke waa kilọ pe ti wahala kankan ba bẹ silẹ l'Ọṣun, Oyetọla ni ki gbogbo awọn eeyan mu o.

No comments:

Post a Comment