Ẹgbẹ oṣelu Labour Party nipinlẹ Ọṣun ti ke si ajọ eleto idibo ijọba ibilẹ l'Ọṣun, OSSIEC, lati sun eto idibo to yẹ ko waye lọjọ Satide ọsẹ yii siwaju fungba diẹ.
Amofin Bọde Babalọla to gbẹnusọ fun gbogbo awọn alaga ati kanselọ ti wọn gba fọọmu lati dije ninu idibo yii ṣalaye pe ajọ OSSIEC ko mura silẹ fun idibo naa.
O ni o han gbangba pe ko si eto aabo to peye nilẹ bayii fun ẹmi awọn oludije ati oludibo pẹlu oniruuru nnkan to n ṣẹlẹ kaakiri ipinlẹ Ọṣun bayii.
Babalọla ṣalaye pe gbogbo awọn nnkan idibo to yẹ ki ajọ OSSIEC ti ko fun awọn oludije ati ẹgbẹ oṣelu ni wọn ko tii ri, bẹẹ, owo to le le ni miliọnu marun naira lawọn san fun idibo naa.
No comments:
Post a Comment