IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 15 February 2025

Ọṣun: Idi ti ẹgbẹ wa ko fi nii kopa ninu idibo ijọba ibilẹ - Oyetọla


Gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla ti ke si awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, lati maṣe kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye kaakiri ipinlẹ Ọṣun lọjọ kejilelogun oṣu keji ọdun yii.


Oyetọla, ẹni to jẹ minisita fun ọrọ okoowo lori omi, sọ pe idajọ ile-ẹjọ kotẹmilọrun ti sọ gbangba pe awọn alaga kansu atawọn kanselọ ẹgbẹ APC ti ijọba Gomina Ademọla Adeleke le kuro lọdun 2022 ni ki wọn pada sibẹ.


O ni ko si alafo kankan nipo alaṣẹ ni gbogbo sẹkiteriati ijọba ibilẹ to wa l'Ọṣun, nitori naa, idibo ti ajọ OSSIEC fẹẹ ṣe ko le lẹsẹ nilẹ rara.


Oyetọla rọ awọn ọmọ ẹgbẹ APC lati fọkanbalẹ, o ni ko si jagidijagan rara, ilana ofin ni wọn yoo fi pada si sẹkiteriati wọn, ti wọn yoo si maa ba iṣẹ lọ.

 

O ni gbogbo ipilẹ ti ajọ OSSIEC duro le lati ṣeto idibo naa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun ti wo lulẹ patapata, nitori naa, ko si idibo ijọba ibilẹ kankan to le rẹsẹ walẹ l'Ọṣun.


Lori idibo 2026, Oyetọla sọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ pe to ba to asiko, gbogbo wọn yoo mọ ibi ti adari ẹgbẹ n lọ..

No comments:

Post a Comment