Awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ni iha Iwọ-Oorun Ọṣun ti ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati yago fun ohunkohun to le fa iyapa ninu ẹgbẹ wọn ṣaaju idibo gomina ọdun 2026.
Nibi ipade kan ti wọn ṣe niluu Iwo laipẹ yii ni awọn agbaagba ọhun ti sọ pe ko bojumu bi awọn eeyan kan ṣe n kọ oniruuru ọrọ kobakungbe mọ ara wọn lori ikanni ayelujara lori ibi to yẹ ki oludije ti wa.
Ninu abajade ipade naa, eleyii ti alaga ẹgbẹ APC niha Iwọ-Oorun Ọṣun, Ọnarebu Akintọla Ọmọlaoye, ka fun awọn oniroyin, ni wọn ti sọ pe igbesẹ naa ko dara to fun ẹgbẹ to n mura silẹ lati gbajọba lọwọ ẹgbẹ to n ṣakoso lọwọ.
Nitori idi eyi, wọn ni ki gbogbo awọn ti wọn n pọnmi oke ru ti odo yii lọọ so ewe agbejẹ mọwọ.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ki ẹnikẹni to sọ ohunkohun nipa ibi ti oludije ẹgbẹ wọn yoo ti wa, gomina ana, Alhaji Adegboyega Oyetọla gbọdọ kọkọ sọ pe ohun ko ṣe saa keji mọ.
Lẹyin eyi ni awọn alakoso ẹgbẹ yoo joko lati mọ ibi to yẹ ki ipo naa lọ lai ṣegbe sẹyin ẹnikẹni pẹlu ilana ibi-ko-ju-ibi, baa ṣe bẹru la bi ọmọ.
Wọn waa rawọ ẹbẹ si awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọṣun lati mọ pe iha Iwọ-Oorun ko tii lanfaani si ipo gomina ri l'Ọṣun, nitori naa, ki wọn faaye gba oludije lati wa latibẹ.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ko si oludije kankan ti wọn ni lọkan lọwọlọwọ, ṣugbọn awọn oloṣelu ti wọn kunju osunwọn lati agbegbe naa pọ jaburata, ti wọn ko si nii doju ti ẹgbẹ naa.
Lara awọn ti wọn wa nibi ipade naa ni igbakeji gomina Ọṣun tẹlẹ, Benedict Alabi, Ọnọrebu Adejare Bello, Ọnarebu Mojeed Alabi, Ọmọọba Dọtun Babayẹmi, Sẹnetọ Mudashiru Hussein, Ọnọrebu Akintọla Ọmọlaoye, Alhaji Gbadebọ Ajao ari bẹẹ bẹẹ lọ.
No comments:
Post a Comment