IROYIN YAJOYAJO

Friday, 28 February 2025

Oṣu kẹta ọdun yii layẹwo awọn to fẹẹ darapọ mọ ajọ Amọtẹkun l'Ọṣun


Ajọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun ti kede pe ọjọ kẹta oṣu kẹta ọdun yii ni ayẹwo yoo bẹrẹ fun gbogbo awọn araalu ti wọn gba fọọmu lati darapọ mọ ajọ naa.


Gẹgẹ bi alukooro wọn, Yusuf Idowu Abass, ṣe fi sita, laarin ọjọ kẹta si ọjọ karun-un ni eto ayẹwo naa yoo waye ni olu ileeṣẹ ajọ ọhun to wa ni Powerline lopopona Ikirun niluu Oṣogbo.

O ni awọn ti wọn ba yege ayẹwo yii ni yoo kopa ninu ayẹwo ara, iyẹn physical fitness exercise, ti yoo waye laarin ọjọ keje si ọjọ kẹjọ oṣu kẹta ọdun yii.

Idowu sọ siwaju pe wọn yoo sare onikilomita kan lati mọ ipo ti ilera ara wọn wa, ṣokoto funfun penpe, aṣọ funfun olobiripo lọrun ati bata funfun ni wọn yoo si wọ fun ere sisa naa.

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn nnkan ti wọn nilo lati mu wa sibi ayẹwo naa niwọnyii: 

- Local Government Identification Certificate 
- National Identification Number (NIN)
- Birth Certificate
- Academic Certificates/Results
- Relevant Credentials (e.g., Trade Test Certificates, Driver’s License, etc.)

Bakan naa ni wọn gbọdọ lọ fun ayẹwo ara wọn nileewosan to jẹ tijọba. 

Atupalẹ bi eto ayẹwo naa yoo ṣe lọ niyii: 

Day 1 - Monday, 3rd March 2025, 7:00 am: Osun East Senatorial District which comprises of Ilesa West LG, Ilesa East LG, Atakumosa East LG, Atakumosa West LG, Oriade LG, Obokun LG, Ife South LG, Ife East and Area Office, Ife Central LG, and Ife North LG.

Day 2 - Tuesday, 4th March 2025, 7:00 am: Osun Central Senatorial District which comprises of Ifelodun LG, Boripe LG, Orolu LG, Irepodun LG, Osogbo LG, Olorunda LG, Boluwaduro LG, Ila LG, Ifedayo LG, and Boripe LG.

Day 3 - Wednesday, 5th March, 2025, 7:00am: Osun West Senatorial District which comprises of Isokan LG, Irewole LG, Ayedaade LG, Ayedire LG, Olaoluwa LG, Iwo LG, Ejigbo LG, Egbedore LG, Ede North LG, and Ede South.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kin-in-ni ọdun yii ni ajọ Amọtẹkun kede pe ki awọn to ba nifẹẹ lati darapọ mọ ajọ naa lọ forukọ silẹ lori ikanni ayelujara, odidi ọsẹ mẹta ni wọn si fi ṣe eleyii.

Alakoso ajọ Amọtẹkun l'Ọṣun, Dokita Adekunle Isaac Ọmọyẹle, ṣalaye pe ko nii si ojuṣaju ninu eto naa, ẹni to ba ti yege lawọn yoo mu.

No comments:

Post a Comment