Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ, to tun jẹ Ọtun Olubadan, Rashidi Ladọja, ti sọ pe irọ funfun balau ni gomina Ọṣun tẹlẹ, Oloye Bisl Akande pa mọ oun lori ọrọ iku Oloye Bọla Ige.
Ladọja ṣalaye pe oun ko figba kankan pagidina idajọ ododo lori ọrọ iku oloogbe naa, bẹẹ ni oun fi gbogbo ara oun jin fun igbẹjọ ọhun titi de ile ẹjọ to ga julọ lorileede yii.
Laipẹ yii ni Oloye Akande sọ nibi ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Edmund Obilo niluu Ibadan pe Ladọja le ni awọn aṣiri kan lọwọ nipa bi awọn agbanipa ṣe pa Bọla Ige.
Akande sọ siwaju pe o dun oun pe awọn eeyan pataki-pataki to yẹ ki wọn tun pese ohun ijinlẹ nipa iṣẹlẹ naa bii Lam Adeṣina ti jade laye.
Ṣugbọn Ladọja sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ Akande, o ni oun ko mọ nnkan kan nipa ẹjọ naa ju eyi ti gbogbo aye mọ lọ.
O kilọ fun Oloye Akande pe ti ko ba pohunda lori irọ to pa mọ oun, ko si bẹbẹ nita gbangba, gbogbo agbara ofin to wa nikawọ oun loun yoo lo lori rẹ.
O ni 'Ọjọ kẹtalelogun oṣu kejila ọdun 2001 ni wọn pa Oloye Bọla Ige, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun ọdun 2003, iyẹn lẹyin oṣu mejidinlogun iṣẹlẹ naa ni mo di gomina.
“Mi o da igbẹjọ naa duro rara, bẹẹ ni ijọba mi ko figba kankan sọ pe a ko ṣẹjọ mọ, koda, a ba ẹjọ naa de ile ẹjọ to ga julọ lorileede yii. Oloye Akande parọ mọ mi. Ki i ṣe igba akọkọ ti awọn eeyan maa sọ pe o maa n purọ niyii, Baba Adebanjọ ti figba kan sọ ninu iwe rẹ pe opurọ ni.
“Gbogbo wa ni inu wa ko dun lori iku Oloye Bọla Ige, o si ka wa lara pupọ. Mo sunmọ Oloye Bọla Ige daadaa nigba ayee wọn”
No comments:
Post a Comment