Lati fopin si wahala iwakusa lọna aitọ ati awọn iwa ipa mi-in niluu Ileṣa ati agbegbe rẹ, awọn ori-ade kan pẹlu awọn aṣaaju niluu naa ti ṣepade papọ pẹlu awọn ti wọn ti sọ ara wọn di ọmọ ganfe nibẹ.
Nibi ipade naa ni wọn ti la wọn lọyẹ lori atubọtan iwa ṣiṣe ẹgbẹ okunkun, hihu iwa janduku ati oniruuru iwa buruku miran.
Lasiko to n dahun ibeere awọn oniroyin nibi eto kan ti awọn to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ iroyin nipinlẹ Ọṣun, League of Veteran Journalists, ṣagbekalẹ rẹ niluu Oṣogbo laipẹ yii ni Aṣiwaju ilẹ Ijeṣa, Oloye Ọlayinka Faṣuyi, ti sọ pe igbesẹ ti n lọ lọwọ lati ṣiṣẹ papọ pẹlu ijọba lojuna ati mu opin de ba bi awọn awakusa lọna aitọ ṣe n ba ilẹ ilu naa jẹ.
O ni nigba ti awọn aṣaaju ilu naa pẹlu awọn ọba alaye kan jokoo, ti wọn si ṣapero lori ipenija eto aabo to n fi ilu naa logbologbo, ni wọn fohun ṣọkan lati ṣepade pẹlu awọn Area Boys.
Faṣuyi ni oniruuru iṣẹ ti wọn le maa ṣe lati mu ki aye wọn rọrun, ki wọn si di ẹni to le da duro, ti ilu Ileṣa ati agbegbe rẹ yoo si wa lalaafia lawọn yannana rẹ fun wọn, ti awọn si ṣeleri lati ran wọn lọwọ lori eyikeyi ti wọn ba fẹẹ ṣe nibẹ.
Nigba to n sọrọ lorii bi ọwọ ṣe tẹ awọn Boko Araamu kan ni Ileṣa laipẹ yii, Faṣuyi ṣalaye pe inu oun dun gidigidi fun iṣẹ takuntakun ti awọn oṣiṣẹ alaabo ṣe, pẹlu ileri pe igbesẹ ti n lọ lọwọ lati ri i pe iru nnkan bẹẹ ko ṣẹlẹ niluu naa mọ.
O ni awọn ti ni alakalẹ lori eto aabo ni ilu Ileṣa bayii ṣugbọn ifọwọsowọpọ awọn ijọba ibilẹ ṣe pataki, bo tilẹ jẹ pe ko si owo lasunwọn ijọba ibilẹ bayii, o ni awọn ti n ba awọn lọbalọba nilẹ Ijeṣa sọrọ lati jawe si eto aabo agbegbe wọn.
Faṣuyi sọ siwaju pe akitiyan Ijesa Mineral Resources Development Forum (IMRDF) ti mu ki iwakusa lọna aitọ dinku pupọ nitori gbogbo igba ni wọn n lọ kaakiri lati la awọn araalu lọyẹ lori ewu to wa ninu fifaaye gba awọn awakusa lọna aitọ wọnyii.
Lai gba owo lọwọ ijọba kankan, o ni awọn ọmọ ajọ naa ti lọ kaakiri ilẹ Ijeṣa lati ọdun marun sẹyin ti wọn ti ṣagbekalẹ rẹ, igbesẹ wọn si ti n so eso rere bayii, nitori tẹlẹtẹlẹ, awọn eeyan ti n sa kuro nidi iṣẹ agbẹ lọ sibi iwakusa, ṣugbọn gbogbo nnkan ti n yatọ bayii.
No comments:
Post a Comment