The Osun Mastermind (TOM) ti sọ pe iwa ọdaju patapata ni bi ajọ to n ṣakoso ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ lorileede yii, iyẹn Nigeria Communications Commission (NCC) pẹlu bi wọn ṣe n gbero lati fi le iye owoG kaadi ipe tawọn araalu n lo.
Lasiko ipade oniroyin oloṣooṣu ti TOM maa n ṣe ni alakoso wọn, Ọjọgbọn Wasiu Oyedokun-Alli ti sọ pe pẹlu inira ti ko ṣe e fẹnusọ ti awọn ọmọ Naijiria n doju kọ bayii, ko yẹ ki ileeṣẹ kankan tun ni in lọkan lati di kun ẹru wọn.
Oyedokun sọ siwaju pe ko si ileeṣẹ ipe (Telcoms) kankan to gbadun dabii alara laarin gbogbo eyi to wa ni Naijiria, ko waa tun yẹ ki NCC faaye gba wọn lati fi kun owo ipe.
TOM ke si ajọ NCC lati tun ero wọn pa lori erongba naa, lai ṣe bẹẹ, Oyedokun ni awọn yoo darapọ mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ orileede yii lati ṣe ifẹhonu han to lagbara.
O ni 'Ohun ti ajọ NCC fẹẹ ṣe yẹn ko bojumu rara, a ko si nii fara mọ ọn. gbesẹ ti yoo mu nnkan dẹ awọn araalu lara lọrun lo yẹ ki lajọlajọ maa gbe bayii, ki i ṣe eyi ti yoo tun di kun iṣoro wa.
'Lọwọlọwọ bayii, ko si ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ kankan ti ko ni abawọn tirẹ, ki lo waa de to jẹ pe ṣe ni wọn fẹẹ di kun iṣoro wa pẹlu fifi pwo kun owo ipe lasiko ti gbogbo nnkan dẹnu kọlẹ yii? Qọn gbọdọ wa nnkan ṣe si i kiakia'
Bakan naa ni TOM gboṣuba fun ijọba ịpinlẹ Ọṣun lori ọrọ awọn ti wọn gba sinu ajọ Imọlẹ Youth Corps ati awọn ẹgbẹrun kan ti wọn fẹẹ gba sinu ajọ Amọtẹkun.
Amọ wọn kilọ pe kijọba gbe igbesẹ kiakia lati ṣatunṣe si ahesọ to n lọ kaakiri pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn pọ ju ninu awọn ti wọn mu.
Gẹgẹ bi TOM ṣe wi, Gomina Adeleke gbọdọ mọ pe ori gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ Ọṣun loun jẹ gomina le, ki i ṣe ẹgbẹ PDP, ohunkohun tijọba ba si n ṣe gbọdọ wa fun gbogbo ọmọ ipinlẹ Ọṣun.
No comments:
Post a Comment