IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 11 February 2025

Nitori aṣọ iwọkuwọ to wọ, awọn araalu sọko ọrọ si Laide Bakare


Kobakungbe ọrọ lawọn eeyan ipinlẹ Ọṣun n sọ ranṣẹ bayii si ọmọbinrin oṣere tiata ilẹ wa nni, Laide Bakare, pẹlu bo ṣe wọ aṣọ to fẹẹ fi gbogbo ihooho ara rẹ han.


Ayẹyẹ kan ti wọn pe ni Osun Comedy Fest ni Laide, ẹni to tun jẹ ọkan lara awọn oluranlọwọ pataki fun Gomina Ademọla Adeleke, ṣagbekalẹ rẹ niluu Oṣogbo lopin ọsẹ to kọja.


Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun awọn eeyan nigba ti wọn ri aṣọ kodoke-kodelẹ alawọ buluu ti ọmọbinrin yii wọ, to si jẹ pe ilaji ọyan rẹ lo wa nita gbangba.


Ninu ọrọ ọkan lara awọn to wa nibi eto naa, Ọgbẹni Awotidoye Kamọrudeen, o ni ohun itiju ni imura Laide yii, o si ja ọpọlọpọ ạwọn ololufẹ rẹ kulẹ pẹlu imura rẹ.


O ni nigba ti abẹsinkawọ gomina ba ṣe bẹẹ mura nita gbangba, bawo nijọba ṣe fẹẹ ba awọn ọdọ sọrọ lati maṣe wọṣọ iwọkuwọ.


Bakan naa ni alaga ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party (NNPP) nipinlẹ Ọṣun, Dokita Tosin Ọdẹyẹmi, ke si Gomina Adeleke lati da Laide Bakare duro gẹgẹ bii oluranlọwọ pataki nitori iwa idojuti gbaa lo hu.


Ọdẹyẹmi ṣalaye pe bawo ni oluranlọwọ pataki fun gomina to yẹ ko jẹ aṣoju ijọba yoo ṣe mura bẹyẹn nita, to tun jẹ pe awọn aṣoju ijọba wa nibi ayẹyẹ naa.


O ni aṣoju rere ati awokọṣe rere lo yẹ ki Bakare jẹ fun awọn ọdọ ipinlẹ Ọṣun, paapaa, awọn ọdọbinrin, ki i ṣe ko tun maa kọ wọn ni imura isọnu.

No comments:

Post a Comment