IROYIN YAJOYAJO

Monday, 17 February 2025

L'Ọṣun, ori ko Ọmọọṣẹ Tinubu yọ lọwọ iku ojiji


Ori lo ko alakoso ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si kikọ ilegbee fawọn araalu, Executive Director, Project Implementation, Federal Housing Authority, Olurẹmi Ọmọwaiye, yọ lọwọ iku ojiji lọsan ọjọ Mọnde ọsẹ yii.


Lati aarọ ti wahala ti bẹrẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC nipinlẹ Ọṣun, o kere tan, eeyan mẹrin lo ti gbẹmi mi, nigba ti ọpọlọpọ si farapa yannayanna.


Ilu Ileṣa la gbọ pe Ọmọwaiye, ẹni to ti figba kan ri jẹ kọmiṣanna nipinlẹ Ọṣun, ti n bọ, bo si ṣe de iwajuu sẹkiteriati Iwọ-Oorun Ileṣa lawọn janduuku kan ya bo ojuutiti, ti wọn si ṣina ibọn bo ọkọ bọọsi to maa n gbe kaakiri.


Wọn fi ibọn dọ gilaasi ọgangan ibi to maa n joko si ninu mọto naa, ti ọta ibọn si lu iho si ara bọọsi ọhun.


Amọ ṣa, a gbọ pe ọkunrin ọmọbibi ilu Ileṣa ọhun ko si ninuu bọọsi funfun naa ̀lasiko iṣẹlẹ naa, lẹyin eyi ni wọn ba ọfiisi rẹ jẹ.

Bakan naa ni dẹrẹba rẹ to farapa wa nileewosan nibi to ti n gba itọju bayii.


No comments:

Post a Comment