Lati le din ainiṣẹ lọwọ ku laarin awọn ọdọ, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti gba ọdọ ẹgbẹrun mẹwaa si ajọ Imọlẹ Youth Corps.
Gẹgẹ bi Gomina Ademọla Adeleke ṣe sọ nibi eto to waye ni Freedom Park niluu Oṣogbo lọjọ Tọsidee ọsẹ yii, igbesẹ naa yoo ṣafikun awọn oṣiṣẹ lẹkajẹka nipinlẹ Ọṣun.
Adeleke ṣalaye pe anfaani pupọ ni eto naa mu wa fun awọn ọdọ ti wọn mu kaakiri wọọdu ojilelọọdunrun o din mẹjọ to wa nipinlẹ Ọṣun lẹnu iṣẹ ti wọn yan laayo nitori wọn yoo lanfaani lati ṣiṣẹ naa.
O ni awọn ẹka ti awọn ọdọ naa yoo ti ṣiṣẹ ni ẹka eto ilera, aabo, itọju agbegbe ati eto ẹkọ, wọn yoo si tun gba idanilẹkọọ si i lati le mu ki ayipada ba eto ọrọ-aje ni ẹsẹkuuku.
O tẹ siwaju pe ijọba oun ti kọkọ ri i daju pe ayika to rọrun wa fun awọn oludaṣẹsilẹ lati ṣiṣẹ l'Ọṣun, bẹẹ nijọba ri i daju pe awọn ọdọ n lo ọgbọn atinuda lati mu idagbasoke ba eto ọrọ-aje kaakiri ipinlẹ Ọṣun.
Adeleke fi kun ọrọ rẹ pe oniruuru anfaani tijọba oun ti la ọna rẹ silẹ lati ọdun meji sẹyin ti pese iṣẹ fun awọn ọdọ ti wọn to ọtalelugba o din mẹwaa.
Gomina parọwa si awọn ọdọ naa lati ṣiṣẹ doju ami ni ẹka ti wọn ba fi wọn si, ki wọn ma si ṣe ja ijọba kulẹ rara, o si ke si kọmiṣanna fun idagbasoke awọn ọdọ, Moshood Ọlagunju, lati ri i pe o n ṣamojuto loorekoore fun ajọ tuntun ọhun.
Ninu ọrọ tirẹ, Moshood Ọlagunju, gboṣuba fun Gomina Adeleke fun agbekalẹ eto naa ati fun ifẹ to ni fun awọn ọdọ.
Bakan naa lo ke si awọn ọdọ lati jẹ aṣoju rere ni ẹka ti wọn ba gbe wọn si.
No comments:
Post a Comment