Alaga agbarijọ ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ọṣun, Dokita Christopher Arapaṣopo, ti kede pe ki awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ ni gbogbo sẹkiteriati ijọba ibilẹ joko sile bẹrẹ lati ọjọ Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun oṣu keji ọdun yii.
Tẹ o ba gbagbe, awọn aṣaaju ẹgbẹ APC l'Ọṣun ti sọ pe idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun ti fun awọn alaga ati kanselọ tijọba PDP le kuro lọdun 2022 laṣẹ lati pada si ọfiisi wọn.
Ṣugbọn ẹgbẹ PDP Ọṣun sọ pe ko si idajọ kankan to fun wọn ni iru aṣẹ bẹẹ, ti Gomina Ademọla Adeleke si ke si Aarẹ Bọla Tinubu lati kilọ fun Alhaji Oyetọla lati maṣe da wahala silẹ l'Ọṣun.
Amọ ṣa, ninu atẹjade Arapaṣopo lo ti sọ pe ọrọ aabo awọn ọmọ ẹgbẹ oun ṣe pataki, bẹẹ lawọn ko le gba ki wọn ṣiṣẹ nibi ti eto aabo ko ba ti muna doko.
Nitori naa, o ni o digba ti alaafia ba too pada ki awọn to gba awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ nijọba ibilẹ laaye lati pada sẹnu iṣẹ.
No comments:
Post a Comment