Aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ẹkun idibo Oriade/Obokun l'Abuja, Hon. Oluwọle Ọkẹ, ti bu ẹnu atẹ lu wahala to bẹ silẹ niluu Ẹsa-Oke nijọba ibilẹ Obokun nipinlẹ Ọṣun laipẹ yii.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kin-in-ni ọdun yii ni igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Ọṣun kede pe Ido-Ajegunlẹ di ọlọba, wọn si fọwọ si yiyan Ọmọọba Timilẹyin Oluyẹmi Ajayi to wa lati orileede Amẹrika gẹgẹ bii Olojudo ti Ido-Ajegunlẹ, eleyii ti ko dun mọ awọn ọmọ ilu naa ninu nitori wọn gbagbọ pe baalẹ wọn lo yẹ kijọba sọ di ojulowo ọba, ki i ṣe ki wọn gbe ara Ileṣa le awọn lori.
Idaji ọjọ Mọnde, ọjọ kẹta oṣu keji ni wahala ọhun bu rẹkẹ, nigba ti awọn ọdọ koju awọn ọlọpaa, ti ibọn si n ro lakọlakọ labala mejeeji lẹyin ti wọn ni awọn kan baalẹ wọn, Oloye Ogunsiji lọ sibi ti awọn ko mọ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe ọlọpaa meje lo farapa lasiko ti awọn ọdọ doju ija kọ wọn.
Ninu ọrọ tirẹ, Ọladiti Awodiran, aṣoju fun Ẹsa-Oke Descendants Union, ṣalaye pe o kere tan, eeyan mẹrin lawọn gbọ pe o ti ku, ti ọpọ si farapa, wọn dana sun mọto Ọwamiran mẹta, ti gbogbo nnkan ko si fararo ninu ilu naa.
Ninu atẹjade kan ti Wọle Ọkẹ fi sita, o ni ibanujẹ nla ni iṣẹlẹ naa jẹ fun oun nitori ko si idi kankan to fi yẹ ki ọrọ naa yọri si ipaniyan tabi biba dukia jẹ, titi to fi de orii aafin Ọwamiran.
O ke si ijọba ipinlẹ Ọṣun lati tete gbe igbimọ ti yoo ṣewadii ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa kalẹ, ki wọn si wa ọna abayọ ti yoo wa titi laelae lorii rẹ.
Bakan naa ni aṣofin yii rọ ijọba lati ri i pe wọn ṣa gbogbo awọn ti wọn wa nidi iwa buruku naa, ki wọn si fi iya to tọ jẹ wọn.
Wọle Ọkẹ sọ siwaju pe gbogbo araalu lo ni ojuṣe lati ri i pe idajọ ododo fẹsẹ mulẹ, ki alaafia si maa jọba nigba gbogbo.
No comments:
Post a Comment