Ọkan pataki lara awọn asiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ni iha Iwọ-Oorun ipinlẹ Ọṣun, Pa Gbadebọ Ajao, ti ke si awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati ri i pe wọn tu jade dibo lasiko idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye lọjọ kejilelogun oṣu keji ọdun yii.
Ajao ṣalaye pe, ti ẹgbẹ APC Ọṣun ba maa kopa ninu idibo naa, yoo jẹ anfaani lati fi idi otitọ mulẹ pe iha Iwọ-Oorun Ọṣun ni ibo pọ si.
Nibi ipade gbogbogbo awọn aṣaaju ẹgbẹ ọhun to waye niluu Iwo laipẹ yii ni baba yii ti sọ pe asiko ti gbogbo wọn gbọdọ ṣiṣẹ papọ lai si iyapa, ki wọn si jẹwọ pe lootọ ni ẹgbẹ naa rinlẹ nibẹ niyii.
O sọ siwaju pe ti awọn ọmọ ẹgbẹ APC ba dibo daadaa, yoo nira fun ẹgbẹ oṣelu kankan lati gbiyanju pe awọn fẹẹ ṣojoro nitori ẹru yoo maa ba wọn.
Ninu ọrọ tirẹ, aṣofin tẹle lati Irewọle, Ayedaade ati Iṣọkan, Hon. Taiwo Oluga ṣalaye pe awọn ko ṣẹṣẹ maa ja fun agbegbe Iwọ-Oorun, ohun to si daju ni pe agbegbe naa lo kan lati gbe oludije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun ninu ẹgbẹ oṣelu APC kalẹ.
Oluga ṣalaye pe gbọnin-gbọnin ni ẹgbẹ APC ni Iwọ-Oorun Ọṣun maa n duro ti ẹgbẹ wọn latẹyin wa ninu gbogbo idibo, asiko si ti to ki ẹgbẹ naa san oore fun wọn.
O ni lootọ lo jẹ pe iha Iwọ-Oorun Ọṣun ni gomina to wa nibẹ lọwọlọwọ ti wa, ṣugbọn ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ onitẹsiwaju, awọn eeyan agbegbe kan ṣoṣo si nijọba rẹ n tẹ lọrun.
Alaga fun ẹgbẹ naa ni ẹkun Iwọ-Oorun Ọṣun, Hon. Olurẹmi Akintọla Ọmọlaoye, ṣalaye pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ lo ti fohun ṣọkan bayii, awọn si n ke si awọn adari ẹgbẹ APC lati faaye gba wọn lati gbe ọmọ-oye kalẹ ninu ibo gomina ọdun 2026.
Ọmọlaoye ke si awọn ọmọ ẹgbẹ, paapaa, awọn ọdọ, lati dẹkun igbesẹ to le tabuku agbegbe naa, ki wọn si ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agbaagba fun aṣeyọri erongba ti wọn gbe dani.
No comments:
Post a Comment