IROYIN YAJOYAJO

Friday, 21 February 2025

Idibo ijọba ibilẹ: Adeleke paṣẹ pe ko gbọdọ si igbokegbodo ọkọ lọjọ Satide


Gomina Ademọla Adeleke ti kede pe ko gbọdọ si igbokegbodo ọkọ laarin aago marun idaji si aago marun irọlẹ ọjọ Satide, ọjọ kejilelogun oṣu keji ọdun yii.


Nini atẹjade ti agbẹnusọ fun gomina, Mallam Ọlawale Rasheed fi sita lo ti ni eleyii ko ṣẹyin eto idibo ijọba ibilẹ to yoo waye ni Satide.


O ni igbesẹ naa yoo dena bi awọn kan ṣe maa n ko awọn janduku kaakiri lasiko idibo lati da omi alaafia agbegbe ru.


Atẹjade naa fi kun un pe awọn ẹṣọ alaabo, awọn oniroyin atawọn ajafẹtọ ọmọniyan ti wọn foruko silẹ nikan ni wọn yoo lanfaani lati rin kaakiri.

No comments:

Post a Comment