IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 8 February 2025

Gomina Ẹdẹ ni Adeleke, ki i ṣe gomina ipinlẹ Ọṣun - Taiwo Oluga


Aṣofin ana to ṣoju awọn eeyan Irewọle, Ayedaade ati Iṣọkan nile igbimọ aṣofin apapọ, Hon. Taiwo Oluga, ti bu ẹnu atẹ lu bi gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ṣe dojuu gbogbo iṣẹ idagbasoke kọ ilu abinibi rẹ, Ẹdẹ, nikan.


Oluga ṣalaye pe lati ọdun meji sẹyin ti Adeleke ti wa lori aleefa, ilu Ẹdẹ nikan lo doju kọ, lai ka awọn agbegbe to ku ni iha Iwọ-Oorun Ọṣun si rara, ka to waa sọ nipa gbogbo ipinlẹ.

Nibi ipade awọn adari ẹgbẹ APC ni Iwọ-Oorun Ọṣun, eleyii to waye niluu Iwo lọjọ Furaidee ọsẹ yii ni Oluga ti sọ pe afi bii ẹni pe awọn eeyan ilu Ẹdẹ nikan ni wọn dibo fun Adeleke lo ṣe n ṣejọba.

O ni 'Gbogbo nnkan ti a n ri l'Ọṣun bayii fi han pe Adeleke ki i ṣe gomina wa, gomina ilu Ẹdẹ ni nitori oniruuru iṣẹ idagbasoke ati iyansipo ni wọn n dari si Ẹdẹ, ti wọn si n na owo to jẹ ti gbogbo wa l'Ọṣun le e lori.

'Idi niyii ti a fi n bẹ gomina wa tẹlẹ, Alhaji Isiaq Gboyega Oyetọla, lati tete sọrọ, ki wọn jẹ ka mọ boya awọn fẹẹ lọ fun saa keji tabi bẹẹ kọ, ti wọn ba ti sọ pe awọn ko lọ mọ, gbogbo ọmọ ẹgbẹ APC gbọdọ fun wa lanfaani ni Iwọ-Oorun Ọṣun lati fa oludije kalẹ.

'Ti wọn ba ti fun wa lanfaani, a ni ọpọ awọn to kunju osunwọn, a si maa fẹnuko lori ẹni ti a ba fẹẹ lo, eleyii yoo fun wa lanfaani lati tun fi han gbogbo awọn eeyan Ọṣun bo ṣe yẹ kijọba tiwantiwa ri gan an'

Oluga waa kilọ fun ẹnikẹni to ba n ṣe tako erongba agbegbe naa ninu ẹgbẹ APC lati jawe akiwọwọ sọwọ nitori awọn agbaagba ẹgbẹ n fiye si iwa ti onikaluku n hu.

Bakan naa ni alaga ẹgbẹ APC ni ẹkun Iwọ-Oorun Ọṣun, Hon. Akintọla Ọmọlaoye, sọ pe agbegbe naa yoo ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe anfaani naa ko bọ mọ wọn lọwọ ni kete ti Oyetọla ba ti sọ pe oun ko dupo mọ.

No comments:

Post a Comment