IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 23 February 2025

Gbogbo igbesẹ awọn adari wa lori ọrọ idajọ ile-ẹjọ kotẹmilọrun la fara mọ - Igbimọ Agba Ọṣun


Igbimọ Agba Ọṣun ti kede atilẹyin wọn fun awọn adari ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, lori gbogbo igbesẹ wọn lati ri i pe ohun ti ile-ẹjọ kotẹmilọrun sọ lori ọrọ ijọba ibilẹ l'Ọṣun fẹsẹ mulẹ.


Ninu atẹjade kan ti alaga wọn, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, fọwọ si ni igbimọ naa ti sọ pe lati ọjọ kẹẹdogun oṣu keji ọdun yii ti awọn ti ṣepade gbẹyin niluu Iragbiji lawọn ti n ṣakiyesi gbogbo eto oṣelu ipinlẹ Ọṣun finnifinni.

Wọn sọ siwaju pe gbọn-in-gbọn-in lawọn wa pẹlu awọn aṣaaju ẹgbẹ APC l'Ọṣun lati ri i pe ohun ti idajọ ile-ẹjọ kotẹmilọrun naa sọ lọjọ kẹwaa oṣu keji ọdun yii di mimuṣẹ.

Atẹjade naa sọ siwaju pe, 'A ranṣẹ ibanikẹdun si mọlẹbi awọn ọmọ ẹgbẹ wa ti wọn padanu ẹmi wọn sọwọ awọn tọọgi PDP lasiko ti awọn alaga ti ile ẹjọ da pada fẹẹ wọ sẹkiteriati lọsẹ to kọja.

'A si tun n ṣeleri ifọwọsowọpọ wa pẹlu awọn aṣaaju ẹgbẹ wa, iyẹn, Oloye Bisi Akande, Alhaji Isiaka Gboyega Oyetọla, Sooko Tajudeen Lawal lori gbogbo igbesẹ ti wọn ba n gbe lati ri i pe wọn ṣamuṣẹ idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun naa ati lati le fopin si fifi ẹmi ati dukia awọn ọmọ ẹgbẹ ṣofo lai nidi'.

Bakan naa ni Igbimọ Agba gboriyin fun iwa akọṣẹmọṣẹ ti awọn ẹṣọ alaabo nipinlẹ Ọṣun hu lasiko naa, bẹẹ ni wọn tun rọ wọn lati maṣe tura silẹ rara, to si tun gboriyin fun awọn ọmọ ẹgbẹ APC fun ifara jin wọn.

No comments:

Post a Comment