IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 25 February 2025

Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi kọ lẹta sawọn oṣiṣẹ ijọba l'Ọṣun


Ọkan pataki lara awọn agbaagba nipinlẹ Ọṣun, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, ti kọ lẹta si awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun, paapaa, awọn ti wọn n ṣiṣẹ nijọba ibilẹ, lati yago fun iwa to le sọ wọn di ohun elo lọwọ awọn oloṣelu.


Ẹ oo ranti pe latari awuyewuye ti idibo ijọba ibilẹ mu lọwọ l'Ọṣun, ẹgbẹ oṣiṣẹ, NLC, paṣẹ pe ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa nijọba ibilẹ joko sile titi digba ti alaafia yoo fi jọba.

Ṣugbọn Ẹnjinia Akinwumi ṣalaye pe igbesẹ NLC naa ti lọ ju, o ni o ti han gbangba pe awọn oṣiṣẹ naa ti sọ ara wọn di irinṣẹ lọwọ awọn oloṣelu kan eleyii to si tako ilana iṣẹ wọn gẹgẹ bii oṣiṣẹ ijọba.

O ni, "Mo mọ pe awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ jẹ ojulowo ọmọbibi ipinlẹ Ọṣun to yẹ ki wọn ṣa ipa wọn fun alaafia, iduroore, idagbasoke ati itẹsiwaju ipinlẹ Ọṣun.

"Mo mọ pe, gẹgẹ bii eniyan, ẹ ni ẹtọ si erongba yin lori ẹgbẹ oṣelu ti ẹ ba fẹ, bẹẹ ni mo mọ pe, gẹgẹ bii oṣiṣẹ ijọba, ẹ ko gbọdọ gbe ẹgbẹ oṣelu kankan kari, ojuṣe yin ni lati ri i pe ẹ ṣiṣẹ bo ti tọ nijọba ibilẹ.

"Ireti araalu ni pe ki ẹ fi imọ ati iriri akọsẹmọṣẹ ti ẹ jẹ ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn aṣaaju to ba wa nijọba ibilẹ yin lai fi ti ẹgbẹ oṣelu yoowu to ba jẹ ṣe.

"Ọba mẹwaa, igba mẹwaa ni, o di dandan ki ayipada wa ninu ẹgbẹ oṣelu to ba n dari yin, ṣugbọn ojuṣe tiyin ni lati tẹriba fun awọn aṣiwaju yoowu to ba wa nibẹ.

"Fun atẹnumọ, ojuṣe ẹgbẹ oṣelu ni lati dupo fun ipo adari ni gbogbo ẹka iṣejọba. Fun ijọba tiwantiwa lati tẹ siwaju, ko si fẹsẹ rinlẹ lorileede Naijiria, idije-dupo yoo maa wa ni gbogbo igba.

"O waa pọn dandan, nitorii ifẹ ilu, ki awọn oṣiṣẹ ijọba yago fun iwa to le sọ wọn di agboṣelu-kari.

"Gẹgẹ bii agba ọmọbibi ipinlẹ Ọṣun, mo fẹẹ gba awọn oṣiṣẹ ijọba ni gbogbo awọn ijọba ibilẹ wa niyanju lati maṣẹ sọ ara wọn di oloṣelu, ki wọn pada sẹnu iṣe wọn.

"Ki wọn fi oṣelu silẹ fun awọn oloṣelu, ki wọn je ki awọn oloṣelu ṣe ohun to tọ, paapaa, niwọn igba ti iru igbesẹ bẹẹ ba ti jẹ eyi ti yoo ṣanfaani fun ijọba ibilẹ wọn atipinlẹ Ọṣun lapapọ"

No comments:

Post a Comment