Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun, to tun jẹ minisita fun ọrọ okoowo ori-omi lorileede yii, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti sọ pe ko si ootọ kankan ninu ẹsun ti Gomina Ademọla Adeleke fi kan oun pe oun fẹẹ da ipinlẹ Ọṣun ru.
O ni ko si akọsilẹ nipa oun lati ọdun mẹẹdogun sẹyin ti ẹnikẹni fi le sọ pe oun le ṣe iru nnkan bẹẹ.
Bakan naa ni atẹjade kan lati ẹka iroyin Oyetọla ni wọn sọ pe minisita naa ko le lọwọ ninu ohunkohun to le da omi alaafia ipinlẹ Ọṣun ru laelae.
"Fun odidi ọdun mẹrin to fi ṣakoso Ọṣun, o ṣafihan ara rẹ gẹgẹ bii ẹni alaafia, ẹni to bọwọ fun ofin, to si korira jagidijagan. To ba jẹ pe oniwahala ni, i ba ja fitafita nigba ti wọn ṣeru ibo lati le e nijọba lọdun 2022.
"Bakan naa, ni ọdun 2022, nigba ti Gomina Ademọla Adeleke lo gbogbo agbara rẹ lati le awọn alaga ati kanselọ kansu tawọn araalu dibo yan danu, Oyetọla, gẹgẹ bii adari wa, ko sọrọ jagidijagan rara, dipo bẹẹ, ṣe lo ṣaaju awọn ọmọ ẹgbẹ lọ si kootu.
"Pẹlu idunnu, ẹgbẹ oṣelu rẹ jawe olubori ni ile ẹjọ kotẹmilọrun lọsẹ to kọja. Gẹgẹ bii adari to fẹran alaafia, o parọwa si awọn ẹṣọ alaabo lati ri i pe wọn fi idi idajọ ododo ile ẹjọ yii mulẹ. Bawo wa ni iru eeyan bẹẹ yoo ṣe maa gbimọ lati da ilu ru. Mo ro pe ẹnikẹni to ba n fẹsun kan Oyetọla pe o fẹẹ da wahala silẹ ni lati lọ fun ayẹwo ọpọlọ''
Oyetọla waa parowa si Adeleke lati bọwọ fun idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun, dipo ko maa ba a lorukọ jẹ, eleyii ti ko fẹsẹ mulẹ labẹ ofin.
No comments:
Post a Comment