IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 2 January 2025

Ọlaja ti fori gbọgbẹ o! Biṣọọbu Ọlaribigbe fẹẹ ba tọkọtiyawo pari ija, ni ọkọ ba gun un lọbẹ pa


Oludasilẹ ijọ Empowerment International to wa lagbegbe BCGA niluu Osogbo nipinle Ọṣun, Biṣọọbu Shina Ọlaribigbe, lo ti dero ọrun apapandodo bayii pẹlu bi ọkunrin kan ṣe gun un lọbẹ pa. 


A gbọ pe obinrin kan to jẹ ogbufọ nileejọsin Ọlaribigbe ni oun ati ọkọ rẹ maa n figba gbogbo ni gbolohun asọ, ti iranṣẹ Ọlọrun yii si maa n ba wọn pari ẹ. 


Bo tilẹ jẹ pe ọtọọtọ lawọn tọkọtaya naa n gbe, sibẹ a gbọ pe wọn ko tii jawe ikọsilẹ fun ara wọn. 


Laarọ ọjọ Tọsidee, ọjọ keji oṣu kinni ọdun yii ni ọkunrin yii lọ si ile iyawo rẹ, ṣugbọn bo ṣe ba Ọlaribigbe nibẹ ni inu bi i, to si fa ọbẹ yọ. 


Ọọgan aya Biṣọọbu lo mu ọbẹ lọ, loju ẹsẹ niyẹn si jade laye. 


Alukoro ọlọpaa Ọṣun, CSP Yẹmisi Ọpalọla fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni tọkọtiyawo naa ti wa lakolo ọlọpaa ni Dugbẹ.

No comments:

Post a Comment