Ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa niluu Akurẹ ti sọ pe afi ki wọn yẹgi fun Dokita Ramon Adedoyin, ẹni ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe o jẹbi iku to pa akẹkọọ Fasiti Ifẹ, Timothy Adegoke.
Onidajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun ṣalaye pe idajọ ile ẹjọ giga naa wa nibamu pẹlu ofin, ṣugbọn adajọ fagile idajọ pe kijọba gbẹsẹ le otẹẹli rẹ atabi pe ki awọn mọlẹbi Adedoyin maa san owo ileewe awọn ọmọ Adedoyin.
Oṣu kọkanla ọdun 2021 ni Adegoke ku sinu otẹẹli Adedoyin, Hilton Hotel niluu Ileefẹ, ọdun 2023 ni adajọ ile ẹjọ giga ilu Oṣogbo dajọ iku fun un.
No comments:
Post a Comment