Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ iwadii lori wahala kan to bẹ silẹ ninu idile Pa Azeez Mutiu latari bi awọn ọmọ baba naa ṣe fẹsun kan akọbi wọn, Mutiu Rauf, pe o ta ile, o si hu oku awọn obi ti wọn sin sibẹ.
Gẹgẹ bi ọkan lara awọn aburo Rauf, Rukayat Adedoyin ṣe ṣalaye, iyawo meji ni baba naa fẹ nigba aye rẹ, o si bi ọmọ meje, ṣugbọn Rauf to jẹ aloku ọlọpaa ni akọbi wọn.
Rukayat sọ siwaju pe ọwọ oun ni gbogbo iwe to nii ṣe pẹlu ile naa, eleyii to wa ni Dada Estate niluu Oṣogbo, wa tẹlẹ, ṣugbọn nigba ti wahala ẹgbọn oun pọ loun ko o le e lọwọ.
O fi kun ọrọ rẹ pe ṣaa deede lẹnikan fi to awọn leti pe ẹgbọn oun atawọn kan ti n hu oku baba ati iya awọn ti wọn sin si ẹyinkule ile naa lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 2024.
O ni bayii lawọn lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ti awọn si ba gbogbo wọn nibẹ, wọn ti hu oku iya jade, ti baba ni wọn n hu lọwọ.
Awọn ọlọpaa paṣẹ pe ki wọn da awọn oku mejeeji pada sibi ti wọn wa tẹlẹ, wọn si fi pampẹ ofin mu Rauf nitori iwadii fidi rẹ mulẹ pe o ti ta ile ọhun.
Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l'Ọṣun, CSP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe lootọ lawọn mu Rauf, ṣugbọn wọn ti gba beeli rẹ nitori ẹsun to lẹtọọ si beeli ni.
Ọpalọla ni iwadii n tẹ siwaju lori ọrọ naa, ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣewadii iwa ọdaran si ni ẹjọ naa wa.
No comments:
Post a Comment